Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:3 - Yoruba Bible

3 “Baba wa kú sinu aṣálẹ̀ láìní ọmọkunrin kankan. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí ó ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA, ṣugbọn ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Baba wa kú li aginjù, on kò si sí ninu ẹgbẹ awọn ti o kó ara wọn jọ pọ̀ si OLUWA ninu ẹgbẹ Kora: ṣugbọn o kú ninu ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀; kò si lí ọmọkunrin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 “Baba wa kú sí aginjù. Kò sí lára àwọn ẹgbẹ́ Kora tí wọ́n kó ara wọn pọ̀ lòdì sí Olúwa, Ṣùgbọ́n ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kò sì fi ọmọkùnrin sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:3
16 Iomraidhean Croise  

Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.


Mo ti ṣe ìlérí pé n óo ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ẹ̀yin eniyan burúkú, tí ẹ̀ ń lòdì sí mi wọnyi. Gbogbo yín ni yóo kú ninu aṣálẹ̀ yìí. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”


Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i.


Àwọn tí ó kú jẹ́ ẹgbaa meje ó lé ẹẹdẹgbẹrin (14,700) láìka àwọn tí ó kú pẹlu Kora.


Selofehadi ọmọ Heferi kò bí ọmọkunrin kankan, àfi ọmọbinrin. Orúkọ àwọn ọmọbinrin Selofehadi ni Mahila, Noa, Hogila, Milika ati Tirisa.


lọ fi ẹjọ́ sun Mose ati Eleasari alufaa ati àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli níwájú Àgọ́ Àjọ pé,


Kí ló dé tí orúkọ baba wa yóo fi parẹ́ kúrò ninu ìdílé rẹ̀ nítorí pé kò ní ọmọkunrin? Nítorí náà, ẹ fún wa ní ilẹ̀ ìní láàrin àwọn eniyan baba wa.”


Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”


Nítorí náà, mo wí fun yín pé ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Nítorí bí ẹ kò bá gbàgbọ́ pé, ‘Èmi ni,’ ẹ óo kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín.”


Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀.


Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.


Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan