Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:16 - Yoruba Bible

16 “OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè gbogbo nǹkan alààyè. Èmi bẹ̀ ọ́, yan ẹnìkan tí yóo máa ṣáájú àwọn eniyan wọnyi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Jẹ ki OLUWA, Ọlọrun ẹmi gbogbo enia, ki o yàn ọkunrin kan sori ijọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Jẹ́ kí Olúwa, Ọlọ́run ẹ̀mí gbogbo ènìyàn, kí ó yan ọkùnrin kan sí orí ìjọ ènìyàn yìí

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:16
20 Iomraidhean Croise  

Nisinsinyii, mo ti ṣe ìpinnu láti kọ́ ilé fún OLUWA Ọlọrun mi, gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀ sí Dafidi, baba mi, pé ọmọ rẹ̀, tí yóo gun orí oyè lẹ́yìn rẹ̀, ni yóo kọ́ ilé ìsìn fún òun.


Wọn yóo dáàbò bo ọba pẹlu idà ní ọwọ́ wọn, wọn yóo sì máa bá a lọ sí ibikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.”


kí erùpẹ̀ tó pada sí ilẹ̀ tí ó wà tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀mí tó pada tọ Ọlọrun tí ó fúnni lọ.


N óo fun yín ní àwọn olùṣọ́ aguntan tí ó wù mí, tí yóo fi ìmọ̀ ati òye bọ yín.


“Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe?


Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”


Èmi ni mo ni ẹ̀mí gbogbo eniyan, tèmi ni ẹ̀mí baba ati ẹ̀mí ọmọ; ẹni yòówù tó bá dẹ́ṣẹ̀ ni yóo kú.


Olùṣọ́ kanṣoṣo ni n óo yàn fún wọn, òun náà sì ni Dafidi, iranṣẹ mi. Yóo máa bọ́ wọn, yóo sì máa ṣe olùṣọ́ wọn.


Dafidi, iranṣẹ mi ni yóo jọba lórí wọn; gbogbo wọn óo ní olùṣọ́ kan. Wọn óo máa pa òfin mi mọ́, wọn óo sì máa fi tọkàntọkàn rìn ní ìlànà mi.


Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”


Mose bá gbadura báyìí pé,


Nítorí náà ẹ bẹ Oluwa ìkórè kí ó rán àwọn òṣìṣẹ́ sí ibi ìkórè rẹ̀.”


“Èmi ni olùṣọ́-aguntan rere. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-aguntan rere, mo ṣetán láti kú nítorí àwọn aguntan.


Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀.


OLUWA Ọlọrun sọ fún Mose pé, “Àkókò ń tó bọ̀ tí o óo kú, pe Joṣua, kí ẹ̀yin mejeeji wá sinu àgọ́ àjọ kí n lè fi ohun tí yóo ṣe lé e lọ́wọ́.” Mose ati Joṣua bá wọ inú àgọ́ àjọ lọ.


Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè?


“Ọba tí ẹ bèèrè fún náà nìyí, ẹ̀yin ni ẹ bèèrè rẹ̀, OLUWA sì ti fun yín nisinsinyii.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan