Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 27:11 - Yoruba Bible

11 Bí baba rẹ̀ kò bá ní arakunrin, ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún ìbátan rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ ọn jùlọ ninu ìdílé rẹ̀. Ìbátan rẹ̀ yìí ni yóo jogún rẹ̀. Èyí yóo máa jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Bi baba rẹ̀ kò ba si lí arakunrin, njẹ ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní rẹ̀ fun ibatan rẹ̀, ti o sunmọ ọ ni idile rẹ̀, on ni ki o jogún rẹ̀: yio si jasi ìlana idajọ fun awọn ọmọ Israeli, gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Tí baba rẹ̀ kò bá ní arákùnrin, fún ará ilé rẹ̀ tí ó bá súnmọ́ jù ní ìdílé rẹ̀ ní ogún ìní rẹ̀, kí ó lè jogún rẹ̀. Èyí gbọdọ̀ jẹ́ ìlànà ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 27:11
7 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.


Bí arakunrin rẹ bá di aláìní tí ó bá sì tà ninu ilẹ̀ rẹ̀, ọ̀kan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ yóo dìde láti ra ohun tí ìbátan rẹ̀ tà pada.


Arakunrin baba tabi ìyá rẹ̀, tabi ọ̀kan ninu àwọn ìbátan rẹ̀ tabi ẹnìkan ninu àwọn ẹbí rẹ̀ le rà á pada. Bí òun pàápàá bá sì di ọlọ́rọ̀, ó lè ra ara rẹ̀ pada.


Bí kò bá ní arakunrin, kí ẹ fi ilẹ̀ ìní rẹ̀ fún àwọn arakunrin baba rẹ̀.


Èyí yóo jẹ́ ìlànà ati òfin fun yín láti ìrandíran yín níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.


Láti ọjọ́ náà ni ó ti sọ ọ́ di òfin ati ìlànà ní Israẹli, títí di òní olónìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan