Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:53 - Yoruba Bible

53 “Àwọn wọnyi ni kí o pín ilẹ̀ náà fún gẹ́gẹ́ bí iye wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

53 Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

53 “Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:53
16 Iomraidhean Croise  

N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan.


Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.


ó ní, “Ẹ̀yin ni n óo fún ní ilẹ̀ Kenaani, bí ohun ìní yín, tí ẹ óo jogún.”


Ó fún wọn ní ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì jogún èrè iṣẹ́ àwọn eniyan náà.


Ikú ni ìpín wọn bí àgùntàn lásánlàsàn, ikú ni yóo máa ṣe olùṣọ́ wọn; ibojì ni wọ́n sì ń lọ tààrà. Wọn yóo jẹrà, ìrísí wọn óo sì parẹ́, Àwọn olódodo yóo jọba lórí wọn ní òwúrọ̀, ibojì ni yóo sì máa jẹ́ ilé wọn.


Ẹ óo pín in fún ara yín ati fún àwọn àlejò tí wọn ń gbé ààrin yín, tí wọ́n sì ti bímọ sí ààrin yín. Ẹ óo kà wọ́n sí ọmọ onílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Ẹ óo pín ilẹ̀ fún àwọn náà.


A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’


OLUWA sọ fún Mose pé,


Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ ati àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kéékèèké. Bí iye eniyan tí ó wà ninu ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ti pọ̀ sí ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún wọn.


Gègé ni kí ẹ fi pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹ̀yà Israẹli. Fún àwọn tí ó pọ̀ ní ilẹ̀ pupọ, sì fún àwọn tí ó kéré ní ilẹ̀ kékeré. Ilẹ̀ tí gègé olukuluku bá mú ni yóo jẹ́ tirẹ̀, láàrin àwọn ẹ̀yà yín ni ẹ óo ti pín ilẹ̀ náà.


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀, nítorí wọn yóo jogún ayé.


Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.


Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe gba gbogbo ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún Mose, ó sì pín in fún àwọn ọmọ Israẹli; ní ẹlẹ́yà-mẹ̀yà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sinmi ogun jíjà.


Àkọsílẹ̀ bí wọn ṣe pín ilẹ̀ Kenaani, tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Jọdani fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí. Eleasari alufaa, Joṣua, ọmọ Nuni, ati àwọn olórí láti inú ìdílé kọ̀ọ̀kan ninu ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe ètò pípín ilẹ̀ náà.


Ohun ìdọ̀tí kan kò ní wọ inú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó bá ń ṣe ohun ẹ̀gbin tabi èké kò ní wọ ibẹ̀. Àwọn tí a ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè Ọ̀dọ́ Aguntan nìkan ni yóo wọ ibẹ̀.


O ti sọ wọ́n di ìjọba ti alufaa láti máa sin Ọlọrun wa. Wọn yóo máa jọba ní ayé.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan