Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:4 - Yoruba Bible

4 wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹ kà iye awọn enia na, lati ẹni ogún ọdún lọ ati jù bẹ̃ lọ; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati fun awọn ọmọ Israeli, ti o ti ilẹ Egipti jade wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun (20) ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:4
6 Iomraidhean Croise  

Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ ati àwọn ọmọ ọmọ Israẹli tí wọ́n lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀: Reubẹni, àkọ́bí rẹ̀,


Satani fẹ́ ta jamba fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí náà ó gbó Dafidi láyà láti kà wọ́n.


Ní ọjọ́ yìí gan-an ni OLUWA mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.


Ní ọjọ́ kinni oṣù keji, ní ọdún keji tí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún Mose ninu Àgọ́ Àjọ, tí ó wà ninu aṣálẹ̀ Sinai, pé,


Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,


Reubẹni ni àkọ́bí Israẹli. Àwọn ọmọ Reubẹni ní ìdílé-ìdílé nìwọ̀nyí: ìdílé Hanoku, ìdílé Palu,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan