Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 26:3 - Yoruba Bible

3 Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Mose ati Eleasari alufa si sọ fun wọn ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, lẹba Jordani leti Jeriko pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 26:3
10 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko.


wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ ka iye àwọn eniyan náà láti ẹni ogún ọdún lọ sókè,” gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose. Àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n jáde láti ilẹ̀ Ijipti nìwọ̀nyí:


Gbogbo àwọn tí Mose ati Eleasari kà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jọdani létí Jẹriko nìwọ̀nyí.


Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.


Láti Òkè Abarimu wọ́n lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jọdani létí Jẹriko.


Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé,


Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani,


OLUWA sin ín sí àfonífojì ilẹ̀ Moabu tí ó dojú kọ Betipeori, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò mọ ibojì rẹ̀ títí di òní olónìí.


Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan