Ṣalumu ọmọ Kore, ọmọ Ebiasafu, ọmọ Kora ati àwọn ará ilé baba rẹ̀. Gbogbo ìdílé Kora ni alabojuto iṣẹ́ ìsìn ninu tẹmpili ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé àgọ́, gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti jẹ́ alabojuto Àgọ́ OLUWA ati olùṣọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀.
Ó sì sọ fún Kora ati àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ní ọ̀la OLUWA yóo fi ẹni tí í ṣe tirẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni mímọ́ hàn. Ẹni tí OLUWA bá sì yàn ni yóo mú kí ó súnmọ́ òun.
ati ohun tí ó ṣe sí Datani ati Abiramu, àwọn ọmọ Eliabu, ọmọ ọmọ Reubẹni. Ẹ ranti bí ilẹ̀ ti lanu, tí ó sì gbé wọn mì ati àwọn ati gbogbo ìdílé wọn, ati àgọ́ wọn, ati gbogbo iranṣẹ ati ẹran ọ̀sìn wọn, láàrin gbogbo Israẹli.