Numeri 24:9 - Yoruba Bible9 Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!” Faic an caibideilBibeli Mimọ9 O ba, o dubulẹ bi kiniun, ati bi abo-kiniun: tani yio lé e dide? Ibukún ni fun ẹniti o sure fun ọ, ifibú si ni ẹniti o fi ọ bú. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” Faic an caibideil |
Nítorí OLUWA sọ fún mi pé, “Bí kinniun tabi ọmọ kinniun ti máa ń kùn lórí ẹran tí ó bá pa, tí kìí bìkítà fún igbe àwọn olùṣọ́ aguntan, tí wọ́n pera wọn jọ, tí wọn ń bọ̀, tí ẹ̀rù ariwo wọn kìí sìí bà á; bẹ́ẹ̀ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo sọ̀kalẹ̀, yóo wá jà lórí òkè Sioni ati àwọn òkè tí ó yí Sioni ká.