Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:8 - Yoruba Bible

8 Ọlọrun kó wọn ti Ijipti wá, ó jà fún wọn gẹ́gẹ́ bí àgbáǹréré. Wọn yóo pa àwọn ọ̀tá wọn run, wọn óo wó egungun wọn, wọn óo sì fi ọfà pa wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ọlọrun mú u lati Egipti jade wá; o ní agbara bi ti agbanrere: on o jẹ awọn orilẹ-ède ti iṣe ọtá rẹ̀ run, yio si fọ́ egungun wọn, yio si fi ọfà rẹ̀ ta wọn li atapoyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:8
18 Iomraidhean Croise  

Ìwọ óo fi ọ̀pá irin fọ́ wọn, o óo sì fọ́ wọn túútúú bí ìkòkò amọ̀.”


Nítorí pé o óo lé wọn sá; nígbà tí o bá fi ọfà rẹ sun ojú wọn.


Àwọn ọfà rẹ mú, wọ́n gún àwọn ọ̀tá ọba lọ́kàn, àwọn eniyan ń wó lulẹ̀ níwájú rẹ.


Ìjọba tí Ọlọrun fún ọ wà lae ati laelae. Ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ ẹ̀tọ́ ni.


Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ.


Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun. Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.


OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.


Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo.


Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Daniẹli, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn aya wọn, wọ́n bá dà wọ́n sinu ihò kinniun. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀, àwọn kinniun ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú.


Ẹ má lòdì sí OLUWA, ẹ má sì bẹ̀rù àwọn eniyan tí ń gbé ilẹ̀ náà. A óo ṣẹgun wọn, nítorí kò sí ààbò fún wọn mọ́. OLUWA wà pẹlu wa, ẹ má bẹ̀rù.”


wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”


OLUWA mú wọn jáde láti Ijipti wá, Ó sì ń jà fún wọn bí àgbáǹréré.


Wo orílẹ̀-èdè Israẹli! Ó dìde dúró bí abo kinniun, ó sì gbé ara rẹ̀ sókè bíi kinniun. Kò ní sinmi títí yóo fi jẹ ẹran tí ó pa tán, tí yóo sì fi mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tán.”


Níbẹ̀ ni ó wà títí Hẹrọdu fi kú. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí àsọtẹ́lẹ̀ nì lè ṣẹ pé, “Láti Ijipti ni mo ti pe ọmọ mi.”


“ ‘N óo da oríṣìíríṣìí ibi sórí wọn, n óo sì rọ òjò ọfà mi sára wọn.


Ọfà mi yóo tẹnu bọ ẹ̀jẹ̀, yóo sì mu àmuyó. Idà mi yóo sì bẹ́ gbogbo àwọn tí wọ́n lòdì sí mi. N kò ni dá ẹnikẹ́ni sí, ninu àwọn tí wọ́n gbógun tì mí, ati àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́, ati àwọn tí wọ́n dì nígbèkùn, gbogbo wọn ni n óo pa.’


“Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá ko yín wọ ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ yìí, tí ẹ bá gba ilẹ̀ náà, tí OLUWA sì lé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè jáde fun yín, àwọn orílẹ̀-èdè bíi Hiti, Girigaṣi, Amori, Kenaani, Perisi, Hifi, Jebusi, àní àwọn orílẹ̀-èdè meje tí wọ́n tóbi jù yín lọ, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ;


Nítorí a ti gbọ́ bí OLUWA ti mú kí Òkun Pupa gbẹ níwájú yín nígbà tí ẹ jáde ní Ijipti, a sì ti gbọ́ ohun tí ẹ ṣe sí Sihoni ati Ogu, àwọn ọba ará Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani, bí ẹ ṣe pa wọ́n run patapata.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan