Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:7 - Yoruba Bible

7 Òjò yóo rọ̀ fún Israẹli ní àkókò rẹ̀, omi yóo jáde láti inú agbè rẹ̀; àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ yóo sì rí omi mu. Ọba wọn yóo lókìkí ju Agagi lọ, ìjọba rẹ̀ ni a óo sì gbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Omi o ṣàn jade lati inu agbè rẹ̀ wá, irú rẹ̀ yio si wà ninu omi pupọ̀, ọba rẹ̀ yio si ga jù Agagi lọ, ijọba rẹ̀ li a o si gbeleke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:7
29 Iomraidhean Croise  

Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀.


Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.


Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn.


Dafidi ṣe akiyesi pé Ọlọrun ti fi ìdí ìjọba òun múlẹ̀ lórí Israẹli, ati pé Ọlọrun ti gbé ìjọba òun ga nítorí àwọn ọmọ Israẹli eniyan rẹ̀.


Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan.


Ahasu-erusi ọba gbé Hamani, ọmọ Hamedata, ará Agagi, ga ju gbogbo àwọn ìjòyè yòókù lọ.


O gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tẹ̀ àwọn eniyan, o fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò mọ̀ rí sì ń sìn mí.


“Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọrun ninu àwùjọ eniyan, ẹ̀yin ìran Israẹli, ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA.”


Gbogbo àwọn ọba yóo máa wólẹ̀ fún un; gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo sì máa sìn ín.


N óo fi ṣe àkọ́bí, àní, ọba tí ó tóbi ju gbogbo ọba ayé lọ.


Ní ọjọ́ iwájú òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ.


Omi yóo máa ṣàn jáde láti orí gbogbo òkè gíga ati gbogbo òkè ńlá, ní ọjọ́ tí ọpọlọpọ yóo kú, nígbà tí ilé ìṣọ́ bá wó lulẹ̀.


Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ará ilé Jakọbu, ẹ̀yin tí à ń fi orúkọ Israẹli pè, ọmọ bíbí inú Juda, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń forúkọ OLUWA búra, tí ẹ jẹ́wọ́ Ọlọrun Israẹli, ṣugbọn tí kì í ṣe pẹlu òdodo tabi òtítọ́.


Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí


Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká, tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ, òpin ti dé bá ọ, okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.


Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae.


Nígbà tí ó wo Amaleki, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé: “Amaleki ni orílẹ̀-èdè tí ó lágbára jùlọ, Ṣugbọn yóo ṣègbé níkẹyìn.”


Nataniẹli wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ìwọ ni ọmọ Ọlọrun, ìwọ ni ọba Israẹli.”


Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”


Ọ̀kan ninu àwọn angẹli meje tí wọ́n ní àwo meje náà tọ̀ mí wá, ó ní, “Wá kí n fi ìdájọ́ tí ń bọ̀ sórí gbajúmọ̀ aṣẹ́wó náà hàn ọ́, ìlú tí a kọ́ sójú ọpọlọpọ omi.


Ó tún wí fún mi pé, “Àwọn omi tí o rí níbi tí aṣẹ́wó náà ti jókòó ni àwọn eniyan ati gbogbo orílẹ̀-èdè.


A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan