Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:6 - Yoruba Bible

6 Ó dàbí àfonífojì tí ó tẹ́ lọ bẹẹrẹ, bí ọgbà tí ó wà lẹ́bàá odò. Ó dàbí àwọn igi aloe tí OLUWA gbìn, ati bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Bi afonifoji ni nwọn tẹ́ lọ bẹrẹ, bi ọgbà lẹba odònla, bi igi aloe ti OLUWA gbìn, ati bi igi kedari lẹba omi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:6
16 Iomraidhean Croise  

Lọti bá gbójú sókè, ó wo gbogbo agbègbè odò Jọdani títí dé Soari, ó rí i pé gbogbo koríko ibẹ̀ ni wọ́n tutù dáradára tí ó dàbí ọgbà OLUWA ati bí ilẹ̀ Ijipti. Ní àkókò náà, OLUWA kò tíì pa ìlú Sodomu ati Gomora run.


Yóo dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń so ní àkókò tí ó yẹ, tí ewé rẹ̀ kì í rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá dáwọ́lé níí máa yọrí sí rere.


Àwọn igi OLUWA ń mu omi ní àmutẹ́rùn, àní àwọn igi kedari Lẹbanoni tí ó gbìn.


Aṣọ rẹ kún fún òórùn oríṣìíríṣìí turari, láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ni wọ́n tí ń fi ohun èlò ìkọrin olókùn dá ọ lára yá.


Mo lọ sinu ọgbà igi eléso, mo lọ wo ẹ̀ka igi tútù ní àfonífojì, pé bóyá àwọn àjàrà ti rúwé, ati pé bóyá àwọn igi èso pomegiranate tí ń tanná.


N óo gbin igi kedari sinu aṣálẹ̀, pẹlu igi akasia ati igi mitili ati igi olifi. N óo gbin igi sipirẹsi sinu aṣálẹ̀, n óo gbin igi firi ati pine papọ̀.


N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo, n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn; n óo mú kí egungun yín ó le, ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.


Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi, ṣugbọn kí ojú má tì mí. Jẹ́ kí ìpayà bá wọn, ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà. Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.


Wọn yóo wá kọrin lórí òkè Sioni, wọn óo sì yọ̀ lórí nǹkan ọ̀pọ̀ oore tí OLUWA yóo ṣe fún wọn: Wọ́n óo yọ̀ nítorí oore ọkà ati waini ati òróró, ati aguntan ati ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù; ayé wọn óo dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, wọn kò ní dààmú mọ́.


Oríṣìíríṣìí igi eléso yóo hù ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji odò náà: ewé àwọn igi náà kò ní rọ, bẹ́ẹ̀ ni èso wọn kò ní tán. Lóṣooṣù ni wọn yóo máa so èso tuntun nítorí pé láti inú tẹmpili ni omi rẹ̀ yóo ti máa sun jáde wá. Èso wọn yóo wà fún jíjẹ, ewé wọn yóo sì wà fún ìwòsàn.”


“Nígbà náà, àwọn òkè ńlá yóo kún fún èso àjàrà, agbo mààlúù yóo sì pọ̀ lórí àwọn òkè kéékèèké. Gbogbo àwọn odò Juda yóo kún fún omi. Odò kan yóo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn láti ilé OLUWA, yóo sì bomi rin àfonífojì Ṣitimu.


Báwo ni àgọ́ rẹ ti dára tó ìwọ Jakọbu, ati ibùdó rẹ ìwọ Israẹli!


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan