Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 24:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí Balaamu rí i pé OLUWA ń súre fún àwọn ọmọ Israẹli, kò lọ bíi ti iṣaaju láti bá OLUWA pàdé. Ṣugbọn ó kọjú sí aṣálẹ̀,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NIGBATI Balaamu ri pe o wù OLUWA lati bukún Israeli, on kò lọ mọ́ bi ìgba iṣaju, lati wá ìfaiya, ṣugbọn o doju rẹ̀ kọ aginjù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 24:1
13 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Balaamu jí ní òwúrọ̀, ó sọ fún àwọn oníṣẹ́ Balaki pé, “Ẹ máa lọ sí ilẹ̀ yín nítorí OLUWA ti sọ pé n kò gbọdọ̀ ba yín lọ.”


Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un.


Balaamu sọ fún Balaki pé, “Dúró ti ẹbọ sísun rẹ, n óo lọ pàdé OLUWA lọ́hùn-ún.”


OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn, Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.


Kò sí òògùn kan tí ó lè ran Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni àfọ̀ṣẹ kan kò lè ran Israẹli. Wò ó! Àwọn eniyan yóo máa wí nípa Israẹli pé, ‘Wo ohun tí Ọlọrun ṣe!’


Ó bá mú Balaamu lọ sórí òkè Peori tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.


Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.


Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.


Ṣé ẹ ranti pé àwọn ni wọ́n tẹ̀lé ìmọ̀ràn Balaamu tí wọ́n sì mú àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ̀ sí OLUWA ní Peori, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni àjàkálẹ̀ àrùn ṣe bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ Israẹli?


Ṣugbọn mo ní àwọn nǹkan díẹ̀ wí sí ọ. O ní àwọn kan láàrin ìjọ tí wọ́n gba ẹ̀kọ́ Balaamu, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti fi ohun ìkọsẹ̀ siwaju àwọn ọmọ Israẹli, tí wọ́n fi ń jẹ oúnjẹ ìbọ̀rìṣà, tí wọ́n tún ń ṣe àgbèrè.


Nisinsinyii, mo mọ̀ dájú pé o óo jọba ilẹ̀ Israẹli, ìjọba Israẹli yóo sì tẹ̀síwájú nígbà tìrẹ.


Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi.


Saulu dáhùn pé, “Ọlọ́run yóo bukun ọ, ọmọ mi, o óo máa ṣe àṣeyọrí ninu gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.” Dafidi bá bá tirẹ̀ lọ, Saulu sì pada sí ilé rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan