Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:9 - Yoruba Bible

9 Mo rí wọn láti òkè gíga, mò ń wò wọ́n láti orí àwọn òkè. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ń dá gbé; wọn kò da ara wọn pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nitoripe lati ori apata wọnni ni mo ri i, ati lati òke wọnni ni mo wò o: kiyesi i, awọn enia yi yio dágbé, a ki yio si kà wọn kún awọn orilẹ-ède.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Láti ṣóńṣó ibi gíga orí àpáta ni mo ti rí wọn, láti orí ibi gíga ni mo ti ń wò wọ́n. Mo rí àwọn ènìyàn tí ń gbé lọ́tọ̀ wọn kò sì ka ará wọn kún ara àwọn orílẹ̀-èdè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:9
15 Iomraidhean Croise  

Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.”


Nígbà náà ni Hamani lọ bá Ahasu-erusi ọba, ó sọ fún un pé, “Àwọn eniyan kan wà tí wọ́n fọ́n káàkiri ààrin àwọn eniyan ati ní gbogbo agbègbè ìjọba rẹ; òfin wọn kò bá ti gbogbo eniyan mu, wọn kò sì pa àṣẹ ọba mọ́. Kò dára kí o gbà wọ́n láàyè ninu ìjọba rẹ.


Nítorí pé, báwo ni àwọn eniyan yóo ṣe mọ̀ pé, inú rẹ dùn sí èmi ati àwọn eniyan rẹ? Ṣebí bí o bá wà pẹlu wa bí a ti ń lọ ni a óo fi lè dá èmi ati àwọn eniyan rẹ mọ̀ yàtọ̀ sí gbogbo aráyé yòókù.”


Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu, iranṣẹ mi, nítorí pé mo wà pẹlu yín. N óo run gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo le yín lọ, ṣugbọn n kò ní pa yín run. Bí ó bá tọ́ kí n jẹ yín níyà, n óo jẹ yín níyà, kìí ṣe pé n óo fi yín sílẹ̀ láìjẹ yín níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu, ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’


“N óo pàṣẹ pé kí wọ́n gbo gbogbo Israẹli jìgìjìgì láàrin gbogbo orílẹ̀-èdè, bí ìgbà tí wọ́n bá fi ajọ̀ ku èlùbọ́, ṣugbọn kóró kan kò ní bọ́ sílẹ̀.


OLUWA, fi ọ̀pá rẹ tọ́ àwọn eniyan rẹ, àní agbo aguntan ìní rẹ, tí wọn ń dá gbé ninu igbó, láàrin ilẹ̀ ọgbà; jẹ́ kí wọ́n máa jẹko ní Baṣani ati ní Gileadi bí ìgbà àtijọ́.


Nítorí náà ẹ jáde kúrò láàrin wọn, ẹ ya ara yín sọ́tọ̀, ni Oluwa wí. Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́, kí n lè gbà yín.


Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.


Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia, àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu, ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini, tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá.


ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa, láti rà wá pada kúrò ninu gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀, ati láti wẹ̀ wá mọ́ láti fi wá ṣe ẹni tirẹ̀ tí yóo máa làkàkà láti ṣe iṣẹ́ rere.


Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan