Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:7 - Yoruba Bible

7 Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 O si bẹ̀rẹsi owe rẹ̀, o si wipe, Balaki ọba Moabu mú mi lati Aramu wá, lati òke-nla ìla-õrún wá, wipe, Wá, fi Jakobu bú fun mi, si wá, ki o fi Israeli ré.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà náà ni Balaamu sọ ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ jáde wí pé: “Balaki mú mi láti Aramu wá, Ọba Moabu láti òkè ìlà-oòrùn wá Ó wí pé, ‘Wá fi Jakọbu bú fún mi; wá, kí o sì jẹ́rìí sí Israẹli.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:7
31 Iomraidhean Croise  

Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu.


Ó ní, “Dìde, lọ sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, ní Padani-aramu, kí o sì fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Labani, arakunrin ìyá rẹ.


Ó sì tún rí i pé Jakọbu gbọ́ ti baba ati ìyá rẹ̀, ó lọ sí Padani-aramu bí wọ́n ti sọ,


Jonatani, ọmọ Ṣimei, arakunrin Dafidi pa á, nígbà tí ó ń fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́.


Ẹni tí ó tẹ̀lé e ni, Eleasari, ọmọ Dodo, ti ìdílé Ahohi, ó wà pẹlu Dafidi nígbà tí wọ́n pe àwọn ará Filistia níjà, tí wọ́n kó ara wọn jọ fún ogun, tí àwọn ọmọ ogun Israẹli sì sá sẹ́yìn.


Jobu tún dáhùn pé,


Jobu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé,


Kí ló dé tí n óo fi bẹ̀rù ní àkókò ìyọnu, nígbà tí iṣẹ́ ibi àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi bá yí mi ká,


N óo la ẹnu mi tòwe-tòwe; n óo fa ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àtijọ́ yọ,


Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri, ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká, bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan.


“Ìwọ ọmọ eniyan, pa àlọ́ kan kí o sì fi òwe bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀.


Mo bá dáhùn pé, “Áà! OLUWA Ọlọrun, wọ́n ń sọ nípa mi pé, ‘Ǹjẹ́ òun fúnrarẹ̀ kọ́ ni ó ń ro òwe yìí, tí ó sì ń pa á mọ́ wa?’ ”


Ní ọjọ́ náà, wọn yóo máa fi yín kọrin ẹlẹ́yà, wọn yóo sì sọkún le yín lórí tẹ̀dùntẹ̀dùn. Wọn yóo wí pé, ‘A ti parun patapata; ó ti pa ìpín àwọn eniyan mi dà; ẹ wò bí ó ti yí i kúrò lọ́dọ̀ mi, ó pín ilẹ̀ wa fún àwọn tí wọ́n ṣẹgun wa.’ ”


Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?”


àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”


N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.”


Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Balaki, dìde, wá gbọ́, fetí sí mi, ọmọ Sipori;


Nígbà tí ó pada dé, ó bá Balaki ati àwọn àgbààgbà Moabu, wọ́n dúró ti àwọn ẹbọ sísun náà.


Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, pé, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú.


Nígbà tí ó wo àwọn ará Keni, ó fi òwe sọ̀rọ̀ nípa wọn báyìí pé: “Ibi ìpamọ́ tí ẹ̀ ń gbé dàbí ìtẹ́ tí ó wà lórí àpáta gíga.


Balaamu tún fi òwe sọ ọ̀rọ̀ wọnyi: “Ta ni yóo là nígbà tí Ọlọrun bá ṣe nǹkan wọnyi?


ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọ̀rọ̀ Balaamu ọmọ Beori nìyí, ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ríran dájúdájú;


Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”


kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́. N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.”


Àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin ati àwọn àgbà ń wá ọ̀nà láti mú un, nítorí wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó pa òwe yìí mọ́, ṣugbọn wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan. Wọ́n bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bá tiwọn lọ.


nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè.


Mo pe ẹ̀yin ọmọ ogun Israẹli níjà lónìí, ẹ yan ọkunrin kan, kí ó wá bá mi jà.”


Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.


Dafidi dáhùn pé, “Ìwọ ń bọ̀ wá bá mi jà pẹlu idà ati ọ̀kọ̀, ṣugbọn èmi ń bọ̀ wá pàdé rẹ ní orúkọ OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun Israẹli, tí ò ń pẹ̀gàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan