Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:12 - Yoruba Bible

12 Ó sì dáhùn pé, “Ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 On si dahùn o si wipe, Emi ha le ṣe aiṣọra lati sọ eyiti OLUWA fi si mi li ẹnu bi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Ó sì dáhùn wí pé, “Ṣé kí n má sọ nǹkan tí Olúwa fi sí mi lẹ́nu?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:12
11 Iomraidhean Croise  

O óo máa bá a sọ̀rọ̀, o óo sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu. N óo gbàkóso ẹnu rẹ ati ẹnu rẹ̀; n óo sì kọ yín ní ohun tí ẹ óo ṣe.


bí ó bá sọ̀rọ̀ dáradára, má ṣe gbà á gbọ́, nítorí ọpọlọpọ ìríra kún inú ọkàn rẹ̀.


Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.”


Balaamu dáhùn pé, “Wíwá tí mo wá yìí, èmi kò ní agbára láti sọ ohunkohun bíkòṣe ohun tí OLUWA bá sọ fún mi.”


Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”


OLUWA ti sọ fún mi pé kí n bukun wọn, Ọlọrun pàápàá ti bukun wọn, èmi kò lè mú ibukun náà kúrò.


Balaamu dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ n kò tí sọ fún ọ pé ohun tí OLUWA bá sọ fún mi ni mo gbọdọ̀ sọ?”


Balaamu bá sọ fún Balaki pé, “Dúró níhìn-ín, lẹ́bàá ẹbọ sísun rẹ, n óo máa lọ bóyá OLUWA yóo wá pàdé mi. Ohunkohun tí ó bá fihàn mí, n óo sọ fún ọ.” Ó bá lọ sórí òkè kan.


bí o tilẹ̀ fún mi ní ààfin rẹ, tí ó sì kún fún fadaka ati wúrà, sibẹsibẹ, n kò ní agbára láti ṣe ohunkohun ju ohun tí OLUWA bá sọ lọ. N kò lè dá ṣe rere tabi burúkú ní agbára mi, ohun tí OLUWA bá sọ ni n óo sọ.”


Nítorí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ kì í ṣe iranṣẹ Oluwa wa Kristi, ikùn ara wọn ni wọ́n ń bọ. Wọn a máa fi ọ̀rọ̀ dídùn ati kí á máa pọ́n eniyan tan àwọn tí kò bá fura jẹ.


Wọ́n ń fi ẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn mọ Ọlọrun, ṣugbọn wọ́n ń sẹ́ ẹ ninu ìwà wọn. Wọ́n jẹ́ ẹlẹ́gbin ati aláìgbọràn, wọn kò yẹ fún iṣẹ́ rere kan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan