Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 23:1 - Yoruba Bible

1 Balaamu sọ fún Balaki pé, “Tẹ́ pẹpẹ meje sí ibí yìí fún mi kí o sì pèsè akọ mààlúù meje ati àgbò meje.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 BALAAMU si wi fun Balaki pe, Mọ pẹpẹ meje fun mi nihin, ki o si pèse akọ-malu meje, ati àgbo meje fun mi nihin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Balaamu wí fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ méje fún mi níbí, kí o sì mú akọ màlúù méje àti àgbò méje wá fún mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 23:1
19 Iomraidhean Croise  

“Ṣugbọn tí ẹ bá sọ fún mi pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun yín, ṣebí àwọn ibi ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ Ọlọrun náà ni Hesekaya ti bàjẹ́, tí ó sì sọ fún àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu pé, ‘Níwájú pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu nìkan ni kí ẹ ti máa sìn.’


Nítorí pé Ọlọrun ran àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru Àpótí Majẹmu OLUWA lọ́wọ́, wọ́n fi mààlúù meje ati àgbò meje rúbọ.


Wọ́n fi akọ mààlúù meje, àgbò meje, ọ̀dọ́ aguntan meje ati òbúkọ meje rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba Hesekaya, ati ilé OLUWA ati ilé Juda. Ọba pàṣẹ pé kí àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni, fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ OLUWA.


Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”


Yẹ̀ẹ̀pẹ̀ ni kí ẹ fi tẹ́ pẹpẹ fún mi, kí ẹ sì máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí rẹ̀, kì báà ṣe aguntan tabi mààlúù. Níbikíbi tí mo bá pa láṣẹ pé kí ẹ ti sìn mí, n óo tọ̀ yín wá, n óo sì súre fún yín níbẹ̀.


Ohun ìríra ni ẹbọ eniyan burúkú lójú OLUWA, ṣugbọn adura olódodo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀.


Wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ bí àwọn eniyan tií wá, wọ́n sì ń jókòó níwájú rẹ bí eniyan mi. Wọ́n ń gbọ́ ohun tí ò ń wí, ṣugbọn wọn kò ní ṣe é; nítorí pé ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n ní ìfẹ́ pupọ, ṣugbọn níbi èrè tí wọn ó jẹ ni ọkàn wọn wà.


Fún ọjọ́ meje tí ẹ óo fi ṣe àjọ̀dún yìí, yóo mú ọ̀dọ́ akọ mààlúù meje ati àgbò meje tí kò ní àbààwọ́n wá fún ẹbọ sísun, ati òbúkọ kọ̀ọ̀kan fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀.


Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Balaki mú Balaamu lọ sí ibi gegele Bamotu Baali níbi tí ó ti lè rí apá kan àwọn ọmọ Israẹli.


Balaki ṣe gẹ́gẹ́ bí Balaamu ti wí, àwọn mejeeji sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.


Balaamu sọ fún Balaki pé, “Kọ́ pẹpẹ ìrúbọ meje kí o sì mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje wá.”


Balaki ṣe ohun tí Balaamu sọ, ó sì fi akọ mààlúù kọ̀ọ̀kan ati àgbò kọ̀ọ̀kan rúbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.


“Ní ọjọ́ keje, ẹ óo máa fi ẹgbọ̀rọ̀ akọ mààlúù meje, àgbò meji ati ọ̀dọ́ àgbò mẹrinla ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan tí kò ní àbààwọ́n rúbọ.


“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin alárèékérekè wọnyi. Nítorí ẹ ti ìlẹ̀kùn ìjọba ọ̀run mọ́ àwọn eniyan, ẹ̀yin fúnra yín kò wọlé, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí wọ́n fẹ́ wọlé, ẹ kò jẹ́ kí wọ́n wọlé. [


Ó ṣe fún wọn! Wọ́n ń rìn ní ọ̀nà Kaini. Wọ́n tẹra mọ́ ọ̀nà ẹ̀tàn Balaamu nítorí ohun tí wọn yóo rí gbà. Wọ́n dá ọ̀tẹ̀ sílẹ̀ bíi Kora, wọ́n sì parun.


Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ló dùn mọ́ OLUWA jù, ìgbọràn ni, tabi ọrẹ ati ẹbọ sísun?” Ó ní, “Gbọ́! Ìgbọràn dára ju ẹbọ lọ, ìfetísílẹ̀ sì dára ju ọ̀rá àgbò lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan