Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:9 - Yoruba Bible

9 Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó bi í pé, “Àwọn ọkunrin wo ni wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ yìí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Ọlọrun si tọ̀ Balaamu wá, o si wipe, Awọn ọkunrin wo ni wọnyi lọdọ rẹ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ọlọ́run tọ Balaamu wá ó sì wí pé, “Ta ni àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ yìí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:9
16 Iomraidhean Croise  

Ó pè é, ó ní, “Hagari, ẹrubinrin Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo ni o sì ń lọ?” Hagari dáhùn pé, “Mò ń sálọ fún Sarai, oluwa mi ni.”


Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”


Ṣugbọn Ọlọrun sọ fún Labani ará Aramea lóru lójú àlá, ó ní, “Ṣọ́ra, má bá Jakọbu sọ ohunkohun, kì báà jẹ́ rere tabi buburu.”


OLUWA bá pe Kaini, ó bi í pé, “Níbo ni Abeli, àbúrò rẹ wà?” Ó dáhùn, ó ní, “N kò mọ̀. Ṣé èmi wá jẹ́ bí olùṣọ́ àbúrò mi ni?”


Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni.


OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”


Bí o ti rí i pé ara òkè kan ni òkúta yìí ti là, láìjẹ́ pé eniyan kan ni ó là á, tí o sì rí i pé ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fadaka ati wúrà túútúú, Ọlọrun tí ó tóbi ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han ọba. Òtítọ́ ni àlá yìí, ìtumọ̀ rẹ̀ sì dájú.”


Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé,


Ní òru ọjọ́ náà, Ọlọrun tọ Balaamu wá, ó ní, “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ọkunrin wọnyi wá bẹ̀ ọ́ pé kí o bá wọn lọ, máa bá wọn lọ, ṣugbọn ohun tí mo bá sọ fún ọ ni o gbọdọ̀ ṣe.”


Balaamu sọ fún wọn pé, “Ẹ sùn níbí ní alẹ́ yìí, bí ó bá di ọ̀la, n óo sọ ohun tí OLUWA bá sọ fún mi fun yín.” Àwọn àgbààgbà náà sì dúró lọ́dọ̀ Balaamu.


Nítorí àwọn Mesaya èké ati àwọn wolii èké yóo dìde. Wọn yóo fi àmì ńlá hàn, wọn yóo sì ṣe iṣẹ́ ìyanu láti tan eniyan jẹ; bí ó bá ṣeéṣe fún wọn, wọn óo tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ.


Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wí fún mi ní ọjọ́ ìdájọ́ pé, ‘Oluwa, Oluwa, a kéde ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní orúkọ rẹ; a lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ; a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu ní orúkọ rẹ.’


Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan