Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:6 - Yoruba Bible

6 Agbára wọn ju tèmi lọ, nítorí náà, wá bá mi ṣépè lé wọn, bóyá bí mo bá bá wọn jagun, n óo lè ṣẹgun wọn, kí n sì lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ mi. Mo mọ̀ dájú pé ibukun ni fún ẹni tí o bá súre fún; ẹni tí o bá ṣépè fún, olúwarẹ̀ gbé!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Njẹ nisisiyi wa, emi bẹ̀ ọ, fi awọn enia yi bú fun mi; nitoriti nwọn lí agbara jù fun mi; bọya emi o bori, ki awa ki o kọlù wọn, ki emi ki o le lé wọn lọ kuro ni ilẹ yi: nitoriti emi mọ̀ pe ibukún ni fun ẹniti iwọ ba bukún, ifibú si ni ẹniti iwọ ba fibú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Nísinsin yìí, wá fi àwọn ènìyàn wọ̀nyí bú, nítorí wọ́n ní agbára jù fún mi. Nípa ṣíṣe èyí èmi ó ṣẹ́gun wọn, kí n sì lé wọn kúrò ní ilẹ̀ yìí. Nítorí tí mo mọ̀ pé ìbùkún ni fún àwọn tí ìwọ bá bùkún, ìfibú sì ni ẹni tí ìwọ bá fi bú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:6
23 Iomraidhean Croise  

N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.”


Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”


Iranṣẹ tí ọba rán lọ pe Mikaaya wí fún un pé, “Gbogbo àwọn wolii yòókù ni wọ́n ti fi ohùn ṣọ̀kan tí wọ́n sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere fún ọba, ìwọ náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ó bá tiwọn mu, kí o sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere.”


Ahabu ọba Israẹli bá pe àwọn wolii bí irinwo (400) jọ, ó bi wọ́n pé ṣé kí òun lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi àbí kí òun má lọ? Wọ́n dá a lóhùn pé, “Máa lọ, nítorí OLUWA yóo jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́, yóo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí rẹ̀.”


Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”


nítorí pé wọn kò gbé oúnjẹ ati omi lọ pàdé àwọn ọmọ Israẹli, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ Balaamu lọ́wẹ̀ láti máa gbé àwọn ọmọ Israẹli ṣépè, ṣugbọn Ọlọrun wa yí èpè náà pada sí ìre fún Israẹli.


Kí wọn máa ṣépè, ṣugbọn kí ìwọ máa súre. Kí ojú ti àwọn alátakò mi, kí inú èmi, iranṣẹ rẹ, sì máa dùn.


Bí ológoṣẹ́ tí ń rábàbà kiri, ati bí alápàáǹdẹ̀dẹ̀ tí ń fò ká, bẹ́ẹ̀ ni èpè tí kò nídìí, kì í balẹ̀ síbìkan.


Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.


Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”


Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.”


N óo sọ ọ́ di eniyan pataki, ohunkohun tí o bá sọ, n óo ṣe é. Jọ̀wọ́ wá bá mi ṣépè lé àwọn eniyan wọnyi.”


Balaki sọ fún Balaamu pé, “Jẹ́ kí á lọ sí ibòmíràn tí o ti lè rí wọn. Apákan wọn ni o óo rí, o kò ní rí gbogbo wọn, níbẹ̀ ni o óo ti bá mi ṣépè lé wọn.”


Balaki sọ fún Balaamu pé, “N óo mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá Ọlọrun yóo gbà pé kí o bá mi ṣépè lé àwọn eniyan náà níbẹ̀.”


Ó dùbúlẹ̀, ó ba bíi kinniun, bí abo kinniun tí ó sùn, ta ló lè jí i dìde? Ibukun ni fún ẹni tí ó bá súre fún Israẹli, ẹni tí ó bá sì gbé Israẹli ṣépè, olúwarẹ̀ gbé!”


Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀.


nítorí pé, nígbà tí ẹ̀ ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, wọn kò gbé oúnjẹ ati omi pàdé yín. Kàkà bẹ́ẹ̀, Balaamu ọmọ Beori ará Petori, ní Mesopotamia, ni wọ́n bẹ̀ pé kí ó wá gbé yín ṣépè.


Lẹ́yìn náà, Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu, dìde láti bá Israẹli jagun, ó ranṣẹ sí Balaamu, ọmọ Beori, láti wá fi yín gégùn-ún.


Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan