Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:4 - Yoruba Bible

4 Àwọn ará Moabu ranṣẹ sí àwọn olórí Midiani pé, “Àwọn eniyan wọnyi yóo run gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká wa bí ìgbà tí mààlúù bá jẹ koríko ninu pápá.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Moabu si wi fun awọn àgba Midiani pe, Nisisiyi li awọn ẹgbẹ yi yio lá ohun gbogbo ti o yi wa ká, bi akọmalu ti ilá koriko igbẹ́. Balaki ọmọ Sippori si jẹ́ ọba awọn ara Moabu ni ìgba na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Moabu sọ fún àwọn àgbàgbà Midiani pé, “Nísinsin yìí ni àwọn wọ̀nyí yóò lá gbogbo ohun tí ó yí wa ká, bí màlúù ṣe ń jẹ koríko tí ó wà nínú oko.” Bẹ́ẹ̀ ni Balaki ọmọ Sippori, tí ó jẹ́ ọba Moabu nígbà náà,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:4
13 Iomraidhean Croise  

Adadi ati àwọn iranṣẹ baba rẹ̀ wọnyi kúrò ní Midiani, wọ́n sì lọ sí Parani. Ní Parani yìí ni àwọn ọkunrin mìíràn ti para pọ̀ mọ́ wọn, tí gbogbo wọ́n sì jọ lọ sí Ijipti. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Farao, ọba Ijipti, ó fún Adadi ní ilé ati ilẹ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún un déédé.


Ẹnu ya àwọn ìjòyè Edomu, ojora sì mú gbogbo àwọn olórí ní ilẹ̀ Moabu, gbogbo àwọn tí ń gbé Kenaani sì ti kú sára.


Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Nígbà tí Balaki ọmọ Sipori, ọba Moabu rí gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli ṣe sí àwọn ará Amori,


Àwọn àgbààgbà Moabu ati Midiani mú owó iṣẹ́ aláfọ̀ṣẹ lọ́wọ́, wọ́n tọ Balaamu wá, wọ́n sì jíṣẹ́ Balaki fún un.


Mo wo ọjọ́ iwájú rẹ, mo sì rí ẹ̀yìn ọ̀la rẹ. Ìràwọ̀ kan yóo jáde wá láàrin àwọn ọmọ Jakọbu, ọ̀pá àṣẹ yóo ti ààrin àwọn ọmọ Israẹli jáde wá; yóo run àwọn àgbààgbà Moabu, yóo sì wó àwọn ará Seti palẹ̀.


Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Israẹli mú ọmọbinrin Midiani wọlé lójú Mose ati gbogbo àwọn eniyan, níbi tí wọ́n ti ń sọkún lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ níwájú OLUWA.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Wọ́n pa àwọn ọba Midiani maraarun pẹlu. Orúkọ wọn ni: Efi, Rekemu, Suri, Huri ati Reba. Wọ́n pa Balaamu ọmọ Beori pẹlu.


Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí?


Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe nǹkan tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún meje.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan