Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:11 - Yoruba Bible

11 àwọn eniyan kan, tí wọ́n wá láti Ijipti, tẹ̀dó sórí gbogbo ilẹ̀ òun. Ó fẹ́ kí n wá bá òun ṣépè lé wọn, kí ó lè bá wọn jà, kí ó sì lè lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Kiyesi i, awọn enia kan ti ilẹ Egipti jade wá, ti o bò oju ilẹ: wá nisisiyi, fi wọn bú fun mi; bọya emi o le bá wọn jà, emi a si lé wọn lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 ‘Àwọn ènìyàn kan ti ilẹ̀ Ejibiti jáde wá tí wọ́n bo ojú ilẹ̀. Nísinsin yìí, wá, kí o wá fi wọ́n bú fún mi. Bóyá Èmi yóò lè bá wọn jà, èmi ó sì lé wọn jáde.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:11
8 Iomraidhean Croise  

Kí àwọn eniyan máa sìn ọ́, kí àwọn orílẹ̀-èdè sì máa tẹríba fún ọ. Ìwọ ni o óo máa ṣe olórí àwọn arakunrin rẹ, àwọn ọmọ ìyá rẹ yóo sì máa tẹríba fún ọ. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé ọ, òun ni èpè yóo mọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì súre fún ọ, ìre yóo mọ́ ọn.”


Balaamu dáhùn pé, “Balaki ọba àwọn ará Moabu ni ó rán wọn sí mi pé,


Ọlọrun sọ fún Balaamu pé, “Má bá wọn lọ, má sì ṣépè lé àwọn eniyan náà nítorí ẹni ibukun ni wọ́n.”


Nígbà náà ni Balaki sọ fún Balaamu pé, “Kí ni ò ń ṣe sí mi yìí? Mo mú ọ wá láti ṣépè lé àwọn ọ̀tá mi, ṣugbọn ò ń súre fún wọn.”


Balaamu bá bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe sọ̀rọ̀, ó ní: “Láti Aramu, Balaki mú mi wá, ọba Moabu mú mi wá láti àwọn òkè ìlà oòrùn. Ó sọ pé, ‘Wá ba mi ṣépè lé Jakọbu, kí o sì fi Israẹli ré.’


Balaki bá bínú sí Balaamu gidigidi, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ọwọ́ lu ọwọ́. Ó sì sọ fún Balaamu pé: “Mo pè ọ́ pé kí o wá gbé àwọn ọ̀tá mi ṣépè, ṣugbọn dípò kí o gbé wọ́n ṣépè, o súre fún wọn ní ìgbà mẹta!


Ṣugbọn n kò fetísí ọ̀rọ̀ Balaamu; nítorí náà ìre ni ó sú fun yín, mo sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.


Ó bi Dafidi pé, “Ṣé ajá ni mí ni, tí o fi ń mú ọ̀pá tọ̀ mí bọ̀?” Ó fi Dafidi bú ní orúkọ oriṣa rẹ̀,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan