Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 22:1 - Yoruba Bible

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣí kúrò, wọ́n lọ pa àgọ́ wọn sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní òdìkejì Jọdani tí ó kọjú sí Jẹriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 AWỌN ọmọ Israeli si ṣí, nwọn si dó si pẹtẹlẹ̀ Moabu li apa keji Jordani ti o kọjusi Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà àwọn ọmọ Israẹli rin ìrìnàjò lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu wọ́n sì pa ibùdó lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jordani tí ó kọjá lọ sí Jeriko.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 22:1
14 Iomraidhean Croise  

Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn,


láti Bamotu wọ́n ṣí lọ sí àfonífojì tí ó wà ní ilẹ̀ àwọn Moabu ní ìsàlẹ̀ òkè Pisiga tí ó kọjú sí aṣálẹ̀.


Mose ati Eleasari alufaa sì pe àwọn eniyan náà jọ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, lẹ́bàá odò Jọdani, létí Jẹriko,


Wọ́n kó wọn wá sọ́dọ̀ Mose ati Eleasari ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ní òdìkejì odò Jọdani, lẹ́bàá Jẹriko.


A kò ní bá wọn pín ninu ilẹ̀ òdìkejì odò Jọdani nítorí pé a ti ní ilẹ̀ ìní tiwa ní ìhà ìlà oòrùn odò Jọdani níhìn-ín.”


ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko. Wọ́n sì ti pín in ní ìdílé-ìdílé.”


Ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani ní òdìkejì Jẹriko, OLUWA sọ fún Mose pé,


Àwọn ni ìlànà ati òfin tí OLUWA ti pa láṣẹ fún Mose fún àwọn ọmọ Israẹli, ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà ìlà oòrùn Jọdani, ní òdìkejì Jẹriko.


Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. Ó ní,


“A gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ọba Amori mejeeji tí wọ́n wà ní òkè odò Jọdani nígbà náà. Ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti àfonífojì Anoni títí dé òkè Herimoni.


Mose gbéra láti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, ó gun orí òkè Nebo lọ títí dé ṣóńṣó òkè Pisiga, tí ó wà ní òdìkejì Jẹriko. OLUWA sì fi gbogbo ilẹ̀ náà hàn án láti Gileadi lọ, títí dé Dani,


Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀.


omi tí ń ṣàn bọ̀ láti òkè dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ́jọ pọ̀ bí òkítì ńlá ní òkèèrè ní ìlú Adamu tí ó wà lẹ́bàá Saretani. Èyí tí ó ń ṣàn lọ sí Òkun Araba tí à ń pè ní Òkun Iyọ̀ gé kúrò, ó sì dá dúró. Àwọn eniyan náà rékọjá sí òdìkejì ìlú Jẹriko.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan