Numeri 21:8 - Yoruba Bible8 OLUWA sọ fún Mose pé, “Fi idẹ rọ ejò amúbíiná kan, kí o gbé e kọ́ sórí ọ̀pá gígùn kan, ẹnikẹ́ni tí ejò bá bù jẹ, tí ó bá wo ejò idẹ náà yóo yè.” Faic an caibideilBibeli Mimọ8 OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Olúwa sọ fún Mose pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.” Faic an caibideil |
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí: “Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí. Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá. Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun, ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.