Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:7 - Yoruba Bible

7 Wọ́n bá wá sọ́dọ̀ Mose, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ nítorí tí a ti sọ̀rọ̀ òdì sí OLUWA ati sí ọ. Gbadura sí OLUWA kí ó mú ejò wọnyi kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mose bá gbadura fún àwọn eniyan náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àwọn ènìyàn sì wá sí ọ̀dọ̀ Mose wọn wí pé, “A ti dá ẹ̀ṣẹ̀ nígbà tí asọ̀rọ̀-òdì sí Olúwa àti sí ìwọ pẹ̀lú. Gba àdúrà pé kí Olúwa mú ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Nígbà náà ni Mose gbàdúrà fún àwọn ènìyàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:7
30 Iomraidhean Croise  

Abrahamu bá gbadura sí Ọlọrun, Ọlọrun sì wo Abimeleki sàn ati aya rẹ̀ ati àwọn ẹrubinrin rẹ̀, tí wọ́n fi lè bímọ,


Ǹjẹ́ nisinsinyii, dá obinrin náà pada fún ọkọ rẹ̀, nítorí pé wolii ni ọkunrin náà yóo gbadura fún ọ, o óo sì yè. Ṣugbọn bí o kò bá dá a pada, mọ̀ dájú pé o óo kú, àtìwọ ati gbogbo àwọn eniyan rẹ.”


Jeroboamu ọba bẹ wolii náà pé, “Jọ̀wọ́, bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì gbadura sí i pé kí ó wo apá mi sàn.” Wolii náà bá gbadura sí OLUWA, apá Jeroboamu ọba sì sàn, ó pada sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.


Nígbà tí Jehoahasi gbadura sí OLUWA, tí OLUWA sì rí ìyà tí Hasaeli fi ń jẹ àwọn eniyan Israẹli, ó gbọ́ adura rẹ̀.


Lẹ́yìn ìgbà tí Jobu gbadura fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta tán, OLUWA dá ọrọ̀ Jobu pada, ó sì jẹ́ kí ó ní ìlọ́po meji àwọn ohun tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.


Nítorí náà, mú akọ mààlúù meje ati àgbò meje lọ sí ọ̀dọ̀ Jobu kí o rú ẹbọ sísun fún ara rẹ; Jobu iranṣẹ mi yóo sì gbadura fún ọ, n óo gbọ́ adura rẹ̀, n kò sì ní ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ìwà òmùgọ̀ rẹ. Nítorí o kò sọ ohun tí ó tọ́ nípa mi gẹ́gẹ́ bí Jobu iranṣẹ mi ti ṣe.”


Nítorí náà ni ó ṣe wí pé òun yóo pa wọ́n run, bí kì í bá ṣe ti Mose, àyànfẹ́ rẹ̀, tí ó dúró níwájú rẹ̀, tí ó sì ṣìpẹ̀, láti yí ibinu OLUWA pada, kí ó má baà pa wọ́n run.


Nígbàkúùgbà tí ó bá ń pa wọ́n, wọn á wá a; wọn á ronupiwada, wọn á sì wá Ọlọrun tọkàntọkàn.


Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, ẹ bá mi bẹ OLUWA Ọlọrun yín ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré yìí, kí ó jọ̀wọ́ mú ikú yìí kúrò lọ́dọ̀ mi.”


Ṣugbọn Mose bẹ OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kí ló dé tí inú fi bí ọ tóbẹ́ẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ, àwọn tí o fi agbára ati tipátipá kó jáde láti ilẹ̀ Ijipti?


Ní ọjọ́ keji, Mose wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ ti dẹ́ṣẹ̀ ńlá, n óo tún gòkè tọ OLUWA lọ, bóyá n óo lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”


Farao dáhùn, ó ní, “N óo fún yín láàyè láti lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín ninu aṣalẹ̀, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ lọ jìnnà; ati pé, mo fẹ́ kí ẹ bá mi bẹ Ọlọrun yín.”


Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ náà yóo máa fò mọ́ ìwọ, ati àwọn eniyan rẹ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ.” ’ ”


Nígbà náà ni Farao pe Mose ati Aaroni, ó ní, “Ẹ bẹ OLUWA kí ó kó ọ̀pọ̀lọ́ kúrò lọ́dọ̀ èmi ati àwọn eniyan mi, n óo sì jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ rúbọ sí OLUWA.”


OLUWA nígbà tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, wọ́n wá ọ, wọ́n fọkàn gbadura nígbà tí o jẹ wọ́n ní ìyà.


OLUWA bá tún sọ fún mi pé, “Mose ati Samuẹli ìbáà wá dúró níwájú mi, ọkàn mi kò lè yọ́ sí àwọn eniyan wọnyi. Lé wọn kúrò níwájú mi, kí wọ́n máa lọ!


Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun.


“N óo pada sí ibùgbé mi títí wọn yóo fi mọ ẹ̀bi wọn, tí wọn yóo sì máa wá mi nígbà tí ojú bá pọ́n wọn.”


Àwọn eniyan náà sì ké tọ Mose wá fún ìrànlọ́wọ́. Mose gbadura fún wọn, iná náà sì kú.


Ó ní, “Mo ṣẹ̀ ní ti pé mo ṣe ikú pa aláìṣẹ̀.” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Èwo ló kàn wá ninu rẹ̀? Ẹjọ́ tìrẹ ni.”


Simoni dá Peteru lóhùn pé, “Ẹ gbadura sí Oluwa fún mi kí ohunkohun tí ẹ wí má ṣẹlẹ̀ sí mi.”


Ẹ̀yin ará mi, ìfẹ́ ọkàn mi, ati ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọrun fún àwọn Juu, àwọn eniyan mi ni pé kí á gbà wọ́n là.


Inú bí OLUWA sí Aaroni tóbẹ́ẹ̀ tí OLUWA fi ṣetán láti pa á run, ṣugbọn mo gbadura fún Aaroni nígbà náà.


Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn. Adura àtọkànwá olódodo lágbára, nítorí Ọlọrun a máa fi àṣẹ sí i.


Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.


Saulu dá a lóhùn pé, “Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀, ṣugbọn bu ọlá fún mi níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan mi ati gbogbo Israẹli. Bá mi pada lọ, kí n lọ sin OLUWA Ọlọrun rẹ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan