Numeri 21:6 - Yoruba Bible6 OLUWA bá rán ọpọlọpọ ejò amúbíiná sí àwọn eniyan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bù wọ́n jẹ, ọpọlọpọ ninu wọn sì kú. Faic an caibideilBibeli Mimọ6 OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní6 Nígbà náà ni Olúwa rán ejò olóró sí àárín wọn; wọ́n gé àwọn ènìyàn jẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sì kú. Faic an caibideil |
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹranko ilẹ̀ Nẹgẹbu nìyí: “Wọ́n di àwọn nǹkan ìní wọn sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọ́n sì di ìṣúra wọn sí ẹ̀yìn ràkúnmí. Wọ́n ń la ilẹ̀ ìṣòro ati wahala kọjá. Ilẹ̀ àwọn akọ kinniun ati abo kinniun, ilẹ̀ paramọ́lẹ̀ ati ejò amúbíiná tí ń fò. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan tí kò lè ṣe wọ́n ní anfaani.