Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:5 - Yoruba Bible

5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun ati Mose, wọ́n ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó wa wá láti Ijipti, pé kí á wá kú ninu aṣálẹ̀ yìí? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi, burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí ti sú wa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 wọ́n sì sọ̀rọ̀ lòdì sí Ọlọ́run àti Mose, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde láti Ejibiti kí a ba le wá kú sí aginjù yìí? Kò sí oúnjẹ! Kò sì sí omi! Àwa sì kórìíra oúnjẹ tí kò dára yìí!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:5
19 Iomraidhean Croise  

Ọlọrun, olùpèsè ibùjókòó fún àlejò tí ó nìkan wà; ẹni tí ó kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n jáde sinu ìdẹ̀ra, ṣugbọn ó sì fi àwọn ọlọ̀tẹ̀ sílẹ̀ ninu ilẹ̀ gbígbẹ.


Wọ́n sọ̀rọ̀ ìwọ̀sí sí Ọlọrun, wọ́n ní, “Ṣé Ọlọrun lè gbé oúnjẹ kalẹ̀ fún wa ninu aṣálẹ̀?


wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Mose pé, “Ṣé kò sí ibojì ní Ijipti ni o fi kó wa kúrò láti wá kú sí ààrin aṣálẹ̀? Irú kí ni o ṣe sí wa yìí, tí o kó wa kúrò ní Ijipti?


Ni àwọn eniyan náà bá bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose, wọ́n ní, “Kí ni a óo mu?”


Nígbà tí àwọn eniyan Israẹli rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn léèrè pé, “Kí nìyí?” Nítorí pé, wọn kò mọ ohun tíí ṣe. Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Oúnjẹ tí OLUWA fún yín láti jẹ ni.


Àwọn eniyan Israẹli pe orúkọ oúnjẹ náà ní mana, ó rí rínbíntín-rínbíntín, ó dàbí èso igi korianda, ó funfun, ó sì dùn lẹ́nu bíi burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi oyin ṣe.


Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú, ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn, lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.


“Ṣugbọn, àwọn ọmọ náà ṣọ̀tẹ̀ sí mi: wọn kò tẹ̀lé ìlànà mi, wọn kò sì fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé bí eniyan bá tẹ̀lé ni yóo yè, wọ́n sì tún ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. Lẹ́yìn náà mo kọ́ gbèrò ati fi ibinu pa wọ́n run patapata, kí n tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lórí wọn ninu aṣálẹ̀.


Ṣugbọn odidi oṣù kan ni ẹ óo fi jẹ ẹ́, títí tí yóo fi fẹ́rẹ̀ hù lórí yín, tí yóo sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kọ OLUWA tí ó wà láàrin yín sílẹ̀, ẹ sì ti ráhùn níwájú rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ijipti.’ ”


Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.”


Àwọn ọmọ Israẹli bá sọ fún Mose pé, “A gbé! Gbogbo wa ni a óo ṣègbé.


Bẹ́ẹ̀ ni kí á má ṣe dán Oluwa wò, bí àwọn mìíràn ninu wọn ti dán an wò, tí ejò fi ṣán wọn pa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan