Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:4 - Yoruba Bible

4 Àwọn ọmọ Israẹli gbéra láti òkè Hori, wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa, láti yípo lọ lẹ́yìn ilẹ̀ Edomu. Ṣugbọn sùúrù tán àwọn eniyan náà lójú ọ̀nà,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wọ́n rin ìrìnàjò láti òkè Hori lọ sí ọ̀nà tó lọ sí Òkun Pupa, láti kọjá yípo Edomu. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn bínú ní ojú ọ̀nà;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:4
14 Iomraidhean Croise  

Jehoṣafati bèèrè pé, “Ọ̀nà wo ni a óo gbà lọ?” Joramu sì dáhùn pé, “Ọ̀nà aṣálẹ̀ Edomu ni.”


Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí pé àwọn Amaleki ati ará Kenaani ń gbé àfonífojì, ní ọ̀la, ẹ gbéra, kí ẹ gba ọ̀nà Òkun Pupa lọ sinu aṣálẹ̀.”


Mose ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA, gbogbo wọn sì gòkè Hori lọ níwájú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.


Kí ló dé tí ẹ fi mú ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì kí wọ́n má baà rékọjá lọ sinu ilẹ̀ tí OLUWA fi fún wọn?


Wọ́n lọ títí dé àfonífojì Eṣikolu, wọ́n wo ilẹ̀ náà. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n pada dé, wọ́n mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli rẹ̀wẹ̀sì, kí wọn má lè lọ sí ilẹ̀ tí OLUWA ti fi fún wọn.


Wọ́n kúrò ní Òkè Hori wọn lọ sí Salimona.


Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro.


Ṣugbọn ní tiyín, ó ní kí ẹ yipada, kí ẹ sì máa lọ sinu aṣálẹ̀, ní apá ọ̀nà Òkun Pupa.


“Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́.


Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan