Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 21:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani tí ń gbé ìhà gúsù ní Nẹgẹbu Kenaani gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli ń gba ọ̀nà Atarimu bọ̀, ó lọ bá wọn jagun, ó sì kó ninu wọn lẹ́rú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 Ẹni ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha Gusù, gbọ́ pe Israeli gbà ọ̀na amí yọ; nigbana li o bá Israeli jà, o si mú ninu wọn ni igbekun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí ọba Aradi ará Kenaani, tí ń gbé ní gúúsù gbọ́ wí pé Israẹli ń bọ̀ wá ní ojú ọ̀nà Atarimu, ó bá Israẹli jà ó sì fi agbára mú díẹ̀ lára wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 21:1
10 Iomraidhean Croise  

Abramu ṣá ń lọ sí ìhà gúsù ní agbègbè tí à ń pè ní Nẹgẹbu.


Àwọn ará Amaleki ati Kenaani tí ń gbé ibẹ̀ bá wọn jagun, wọ́n ṣẹgun àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì lé wọn títí dé Horima.


Ọba ìlú Aradi, ní ilẹ̀ Kenaani, tí ń gbé Nẹgẹbu gbúròó pé àwọn ọmọ Israẹli ń bọ̀.


Sihoni bá jáde sí wa, òun ati àwọn eniyan rẹ̀, láti bá wa jagun ní Jahasi.


Àwọn ọmọ ogun Ai pa tó mẹrindinlogoji (36) ninu wọn, wọ́n sì lé gbogbo wọn kúrò ní ẹnubodè wọn títí dé Ṣebarimu. Wọ́n ń pa àwọn ọmọ Israẹli bí wọ́n ti ń dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà. Ọkàn àwọn ọmọ Israẹli bá dààmú, àyà wọn sì já.


Àwọn ọmọ ọmọ Keni, àna Mose, bá àwọn ọmọ Juda lọ láti Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ, sí inú aṣálẹ̀ Juda tí ó wà ní apá ìhà gúsù lẹ́bàá Aradi; wọ́n sì jọ ń gbé pọ̀ níbẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan