Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:8 - Yoruba Bible

8 “Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Mú ọpá nì, ki o si pe ijọ awọn enia jọ, iwọ, ati Aaroni arakunrin rẹ, ki ẹ sọ̀rọ si apata nì li oju wọn, yio si tú omi rẹ̀ jade; iwọ o si mú omi lati inu apata na jade fun wọn wá: iwọ o si fi fun ijọ ati fun ẹran wọn mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 “Mú ọ̀pá, náà kí o sì pe ìjọ àwọn ènìyàn jọ, ìwọ àti Aaroni arákùnrin rẹ, kí ẹ sọ̀rọ̀ sí àpáta náà ní ojú wọn, yóò sì tú omi rẹ̀ jáde, ìwọ ó sì fún ìjọ àti ẹran wọn mu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:8
31 Iomraidhean Croise  

Ṣé ohun kan wà tí ó ṣòro fún OLUWA ni? Nígbà tí àkókò bá tó, n óo pada wá sọ́dọ̀ rẹ níwòyí ọdún tí ń bọ̀, Sara yóo bí ọmọkunrin kan.”


O fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n, o sì ń fún wọn ní omi mu láti inú àpáta nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ wọ́n. O ní kí wọ́n lọ gba ilẹ̀ tí o ti ṣèlérí láti fún wọn bí ohun ìní wọn.


Ó la àpáta, omi tú jáde, ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.


Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi, tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.


Nítorí pé OLUWA sọ̀rọ̀, ayé wà; ó pàṣẹ, ayé sì dúró.


Gbé ọ̀pá rẹ sókè kí o na ọwọ́ sórí Òkun Pupa, kí ó sì pín in sí meji, kí àwọn eniyan Israẹli lè kọjá láàrin rẹ̀ lórí ìyàngbẹ ilẹ̀.


Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”


Mú ọ̀pá yìí lọ́wọ́, òun ni o óo máa fi ṣe iṣẹ́ ìyanu.”


OLUWA bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló wà ní ọwọ́ rẹ yìí?” Ó dáhùn pé, “Ọ̀pá ni.”


Mose bá gbé iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọkunrin rẹ̀ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tòun ti ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ rẹ̀.


Mose ati Aaroni ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ OLUWA lójú Farao ati lójú gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀. Aaroni gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè ó sì fi lu omi tí ó wà ninu odò Naili, gbogbo omi tí ó wà ninu odò náà sì di ẹ̀jẹ̀.


Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:


Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde.


Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.


OLUWA sọ fún Mose pé,


ati ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn àfonífojì náà tí ó lọ títí dé ìlú Ari, tí ó lọ dé ààlà Moabu.”


Kànga tí àwọn ọmọ aládé gbẹ́, tí àwọn olórí wà pẹlu ọ̀pá àṣẹ ọba ati ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀ wọn.” Wọ́n sì ṣí kúrò níbẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀ Matana.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.


Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”


Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.


Àwọn alufaa fọn fèrè ogun, bí àwọn eniyan ti gbọ́ ìró fèrè, gbogbo wọn hó yèè! Odi ìlú náà sì wó lulẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun bá rọ́ wọ ààrin ìlú, wọ́n sì gba ìlú náà.


Nígbà tí wọ́n bá fọn fèrè ogun náà gidigidi, tí ẹ sì gbọ́ ìró rẹ̀, kí gbogbo àwọn eniyan hó yèè! Ògiri ìlú náà yóo sì wó. Kí olukuluku àwọn ọmọ ogun wọ inú ìlú náà lọ tààrà.”


Ó wá fi odò omi ìyè hàn mí, tí ó mọ́ gaara bíi dígí. Ó ń ti ibi ìtẹ́ Ọlọrun ati Ọ̀dọ́ Aguntan ṣàn wá.


Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan