Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:6 - Yoruba Bible

6 Mose ati Aaroni kúrò níwájú àwọn eniyan náà, wọ́n lọ dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ, wọ́n dojúbolẹ̀, ògo OLUWA sì farahàn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Mose ati Aaroni si lọ kuro niwaju ijọ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, nwọn si doju wọn bolẹ: ogo OLUWA si hàn si wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Mose àti Aaroni kúrò ní ibi àpéjọ, wọ́n sì lọ dojúbolẹ̀ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ògo Olúwa sì farahàn wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:6
15 Iomraidhean Croise  

Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.


Bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ eniyan Israẹli sọ̀rọ̀, wọ́n wo apá aṣálẹ̀, wọ́n sì rí i pé ògo OLUWA hàn ninu ìkùukùu.


Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.”


OLUWA sì dúró ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu, ó sì pe Aaroni ati Miriamu, àwọn mejeeji sì jáde siwaju.


Bí àwọn eniyan náà ti ń gbèrò láti sọ wọ́n lókùúta pa ni wọ́n rí i tí ògo OLUWA fara hàn ní Àgọ́ Àjọ.


Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀ níwájú àwọn eniyan náà.


Kora kó gbogbo ìjọ eniyan náà jọ sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni; Ògo OLUWA sì farahàn, àwọn eniyan náà sì rí i.


Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀, wọ́n gbadura sí OLUWA, pé, “Ọlọrun, ìwọ ni orísun ìyè, ìwọ yóo ha tìtorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan bínú sí gbogbo ìjọ eniyan bí?”


Nígbà tí Mose gbọ́, ó dojúbolẹ̀,


Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn.


“Kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi kí n lè pa wọ́n run ní ìṣẹ́jú kan.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀.


OLUWA sọ fún Mose pé,


Ó wá tún lọ siwaju díẹ̀ síi, ó dojúbolẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí gbadura pé, “Baba mi, bí ó bá ṣeéṣe, mú kí ife kíkorò yìí fò mí ru. Ṣugbọn kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni ṣíṣe, bíkòṣe ohun tí ìwọ fẹ́.”


Joṣua fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbànújẹ́ hàn, òun ati àwọn àgbààgbà Israẹli dojúbolẹ̀ níwájú Àpótí Majẹmu OLUWA títí di ìrọ̀lẹ́, wọ́n sì ku eruku sórí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan