Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:5 - Yoruba Bible

5 Kí ló dé tí ẹ fi mú wa wá láti Ijipti sí ibi burúkú yìí, kò sí ọkà, kò sí èso ọ̀pọ̀tọ́, tabi èso àjàrà tabi èso pomegiranate, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi mímu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke ti Egipti wá, lati mú wa wá si ibi buburu yi? ki iṣe ibi irugbìn, tabi ti ọpọtọ, tabi ti àjara, tabi ti pomegranate; bẹ̃ni kò sí omi lati mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Kí ni ó dé tí o fi mú wa gòkè kúrò ní Ejibiti wá sí ibi búburú yìí? Ibi tí kò ní oúnjẹ tàbí igi ọ̀pọ̀tọ́, èso àjàrà tàbí pomegiranate. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi tí a ó mu níhìn-ín!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:5
8 Iomraidhean Croise  

Ogoji ọdún ni o fi bọ́ wọn ninu aṣálẹ̀, wọn kò sì ṣe àìní ohunkohun, aṣọ wọn kò gbó, ẹsẹ̀ wọn kò sì wú.


“Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.


Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà, ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun, ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?


Bí mo ṣe dájọ́ àwọn baba ńlá yín ní aṣálẹ̀ ilẹ̀ Ijipti ni n óo dájọ́ yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


O kò tíì kó wa dé ilẹ̀ tí ó lọ́ràá tí ó kún fún wàrà ati oyin, tabi kí o fún wa ní ọgbà àjàrà ati oko. Ṣé o fẹ́ fi júújúú bo àwọn eniyan wọnyi lójú ni, a kò ní dá ọ lóhùn.”


“Níhìn-ín ni Aaroni yóo kú sí, kò ní dé ilẹ̀ tí mo ti ṣe ìlérí pé n óo fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ̀yin mejeeji lòdì sí àṣẹ mi ní Meriba.


nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).


Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan