Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:4 - Yoruba Bible

4 Kí ló dé tí ẹ fi mú àwọn eniyan OLUWA wá sinu aṣálẹ̀ yìí? Ṣé kí àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa lè kú ni?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin fi mú ijọ OLUWA wá si aginjù yi, ki awa ati ẹran wá ki o kú nibẹ̀?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Kí ni ó dé tí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn Olúwa wá sí aginjù yìí, kí àwa àti àwọn ẹran ọ̀sìn wa bá à kú síbí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:4
13 Iomraidhean Croise  

Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,


wọ́n ń wí pé, “Ìbá sàn kí OLUWA pa wá sí ilẹ̀ Ijipti, níbi tí olukuluku wa ti jókòó ti ìsaasùn ọbẹ̀ ẹran, tí a sì ń jẹ oúnjẹ àjẹyó, ju bí ẹ ti kó wa wá sí ààrin aṣálẹ̀ yìí lọ, láti fi ebi pa gbogbo wa kú.”


Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”


“Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.”


Ṣugbọn odidi oṣù kan ni ẹ óo fi jẹ ẹ́, títí tí yóo fi fẹ́rẹ̀ hù lórí yín, tí yóo sì sú yín, nítorí pé ẹ ti kọ OLUWA tí ó wà láàrin yín sílẹ̀, ẹ sì ti ráhùn níwájú rẹ̀ pé: ‘Kí ló dé tí a fi kúrò ní Ijipti.’ ”


Ní Ijipti, à ń jẹ ẹja ati apálà, ẹ̀gúsí, ewébẹ̀, alubọsa ati galiki.


Gbogbo wọn ń kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ó sàn fún wa kí á kúkú kú sí Ijipti tabi ní aṣálẹ̀ yìí.


Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.”


“Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè.


Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan