Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:16 - Yoruba Bible

16 Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nigbati awa si kepè OLUWA, o gbọ́ ohùn wa, o si rán angeli kan, o si mú wa lati Egipti jade wá; si kiyesi i, awa mbẹ ni Kadeṣi, ilu kan ni ipinlẹ àgbegbe rẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 ṣùgbọ́n nígbà tí a sọkún sí Olúwa, ó gbọ́ ẹkún wa, ó sì rán angẹli kan sí wa, ó sì mú wa jáde láti Ejibiti. “Báyìí àwa wà ní Kadeṣi, ìlú tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilẹ̀ rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:16
14 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Farao súnmọ́ àwọn ọmọ Israẹli, tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ojú sókè tí wọ́n rí àwọn ará Ijipti tí wọn ń bọ̀ lẹ́yìn wọn; ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi. Wọ́n kígbe sí OLUWA;


Angẹli Ọlọrun tí ó ti wà níwájú àwọn eniyan Israẹli bá bọ́ sẹ́yìn wọn, ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà níwájú wọn náà bá pada sí ẹ̀yìn wọn.


“Wò ó, mo rán angẹli kan ṣiwaju rẹ láti pa ọ́ mọ́ ní ọ̀nà rẹ, ati láti mú ọ wá sí ibi tí mo ti tọ́jú fún ọ.


N óo rán angẹli mi ṣáájú yín, n óo sì lé àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hamori, àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi jáde.


Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi.


Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”


Bí àwọn baba ńlá wa ṣe lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí wọ́n sì gbé ibẹ̀ fún ìgbà pípẹ́. Àwọn ará Ijipti lo àwọn baba ńlá wa ati àwa náà ní ìlò ẹrú.


“Jọ̀wọ́, gbà wá láàyè láti gba orí ilẹ̀ rẹ kọjá. Àwa ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa kò ní yà kúrò ní ojú ọ̀nà wọ inú oko yín, tabi ọgbà àjàrà yín. Bẹ́ẹ̀ ni a kò ní mu omi kànga yín. Ojú ọ̀nà ọba ni a óo máa rìn títí a óo fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”


Láti Kadeṣi wọ́n lọ sí Òkè Hori, lẹ́bàá ilẹ̀ Edomu.


Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti?


Ìdí tí ó fi ṣe èyí ni pé, ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ọmọ ọmọ wọn; ó fi agbára ko yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ó sì wà pẹlu yín.


Àpèjúwe ìpín tí ó kan ẹ̀yà Juda lára ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli gbà, tí a pín fún wọn gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn nìyí: Ilẹ̀ náà lọ títí dé apá ìhà gúsù, ní ààlà ilẹ̀ Edomu, títí dé aṣálẹ̀ Sini.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan