Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:11 - Yoruba Bible

11 Mose bá mu ọ̀pá rẹ̀ ó fi lu àpáta náà nígbà meji, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí tú jáde lọpọlọpọ; àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì rí omi mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

11 Mose si gbé ọwọ́ rẹ̀ soke, o si fi ọpá rẹ̀ lù apata na lẹ̃meji: omi si tú jade li ọ̀pọlọpọ, ijọ awọn enia si mu, ati ẹran wọn pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Nígbà náà ni Mose gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè ó sì fi ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ lu àpáta lẹ́ẹ̀méjì. Omi sì tú jáde, gbogbo ìjọ ènìyàn àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sì mu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:11
24 Iomraidhean Croise  

Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbé e lákọ̀ọ́kọ́, OLUWA Ọlọrun wa jẹ wá níyà, nítorí pé a kò tọ́jú rẹ̀ bí ó ti tọ́.”


Dafidi bá dáhùn pé, “Àwọn ọmọ Lefi nìkan ni wọ́n gbọdọ̀ ru Àpótí Majẹmu OLUWA, nítorí àwọn ni Ọlọrun yàn láti máa rù ú, ati láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn rẹ̀ títí lae.”


Ó la àpáta, omi tú jáde, ó sì ṣàn ninu aṣálẹ̀ bí odò.


Ẹni tí ó sọ àpáta di adágún omi, tí ó sì sọ akọ òkúta di orísun omi.


Ìwọ ni o fọ́ àpáta tí omi tú jáde, tí odò sì ń ṣàn, ìwọ ni o sọ odò tí ń ṣàn di ilẹ̀ gbígbẹ.


Ó la àpáta ni aṣálẹ̀, ó sì fún wọn ní omi mu lọpọlọpọ bí ẹni pé láti inú ibú.


Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta; ó sì mú kí ó ṣàn bí odò.


Lóòótọ́ ó lu òkúta tí omi fi tú jáde, tí odò sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn. Ṣé ó lè fún wa ní òkèlè pẹlu, àbí ó lè pèsè ẹran fún àwọn eniyan rẹ̀?”


N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.


Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.


Òùngbẹ kò gbẹ wọ́n, nígbà tí ó mú wọn la inú aṣálẹ̀ kọjá, ó tú omi jáde fún wọn láti inú àpáta, ó la àpáta, omi sì tú jáde.


Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ;


Àwọn ọmọ Aaroni meji kan, ọkunrin, tí wọn ń jẹ́ Nadabu ati Abihu, mú àwo turari wọn, olukuluku fọn ẹ̀yinná sinu tirẹ̀, wọ́n da turari lé e lórí, wọ́n sì fi rúbọ níwájú OLUWA, ṣugbọn iná yìí kì í ṣe irú iná mímọ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún wọn.


“Mú ọ̀pá tí ó wà níwájú Àpótí Majẹmu, kí ìwọ ati Aaroni kó àwọn eniyan náà jọ, kí o sọ̀rọ̀ sí àpáta níwájú wọn, àpáta náà yóo sì tú omi jáde. Bẹ́ẹ̀ ni o óo ṣe fún àwọn eniyan náà ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn ní omi.”


Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”


Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.


Ẹni tí ó mú yín la aṣálẹ̀ ńlá tí ó bani lẹ́rù já, aṣálẹ̀ tí ó kún fún ejò olóró ati àkeekèé, tí ilẹ̀ rẹ̀ gbẹ, tí kò sì sí omi, OLUWA tí ó mú omi jáde fun yín láti inú akọ òkúta,


Nítorí ibinu eniyan kì í yọrí sí ire tí Ọlọrun fẹ́.


Ọlọrun bá la ibi ọ̀gbun kan tí ó wà ní Lehi, omi sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde láti inú ọ̀gbun náà. Lẹ́yìn tí ó mu omi tán, ojú rẹ̀ wálẹ̀, nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Enhakore. Enhakore yìí sì wà ní Lehi títí di òní olónìí.


Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?”


Saulu wí fún Samuẹli pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo ti dẹ́ṣẹ̀. Mo ti ṣe àìgbọràn sí òfin OLUWA ati sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorí pé mo bẹ̀rù àwọn eniyan mi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n fẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan