Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 20:1 - Yoruba Bible

1 Ní oṣù kinni, àwọn ọmọ Israẹli dé aṣálẹ̀ Sini, wọ́n sì ṣe ibùdó wọn sí Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú sí, tí wọn sì sin ín sí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 AWỌN ọmọ Israeli si wá, ani gbogbo ijọ, si aginjù Sini li oṣù kini: awọn enia na si joko ni Kadeṣi; Miriamu si kú nibẹ̀, a si sin i nibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní oṣù kìn-ín-ní, gbogbo àgbájọ ọmọ Israẹli gúnlẹ̀ sí pápá Sini, wọ́n sì dúró ní Kadeṣi. Níbẹ̀ ni Miriamu kú, wọ́n sì sin ín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 20:1
23 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni wọ́n tó yipada tí wọ́n sì wá sí Enmiṣipati (tí ó tún ń jẹ́ Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amaleki ati ti àwọn ará Amori tí ń gbé Hasasoni Tamari.


Ohùn OLUWA ń mi aṣálẹ̀; OLUWA ń mi aṣálẹ̀ Kadeṣi.


Nígbà náà ni Miriamu, wolii obinrin, tíí ṣe arabinrin Aaroni, gbé ìlù timbireli lọ́wọ́, gbogbo àwọn obinrin sì tẹ̀lé e, wọ́n ń lu timbireli, wọ́n sì ń jó.


Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obinrin dúró ní òkèèrè, ó ń wo ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí i.


Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà bá bi ọmọbinrin Farao pé, “Ṣé kí n lọ pe olùtọ́jú kan wá lára àwọn obinrin Heberu, kí ó máa bá ọ tọ́jú ọmọ yìí?”


“Ní ìhà gúsù, ilẹ̀ yín yóo lọ láti Tamari dé àwọn odò Meriba Kadeṣi, títí yóo fi kan odò Ijipti títí lọ dé Òkun-ńlá. Èyí ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìhà gúsù.


Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín.


Miriamu ati Aaroni sọ̀rọ̀ òdì sí Mose nítorí pé ó fẹ́ ọmọbinrin ará Kuṣi ní iyawo.


Bí ọ̀wọ̀n ìkùukùu tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ ti gbéra sókè ni ẹ̀tẹ̀ bo Miriamu, ó sì funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. Nígbà tí Aaroni wo Miriamu ó ri wí pé ó ti di adẹ́tẹ̀.


Wọ́n sì fi Miriamu sí ẹ̀yìn ibùdó fún ọjọ́ meje, àwọn eniyan náà kò sì kúrò níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n mú un pada.


Àwọn eniyan náà lọ, wọ́n sì wo ilẹ̀ náà láti aṣálẹ̀ Sini títí dé Rehobu ati ni ẹ̀bá ibodè Hamati.


Wọn tọ Mose, Aaroni, ati àwọn ọmọ Israẹli lọ ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Parani. Wọ́n sọ gbogbo ohun tí ojú wọn rí, wọ́n sì fi èso tí wọ́n mú wá hàn wọ́n.


Nígbà tí a ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, ó gbọ́ adura wa, ó sì rán angẹli rẹ̀ láti mú wa jáde kúrò ní Ijipti. Nisinsinyii a ti dé Kadeṣi, ìlú kan tí ó wà lẹ́yìn odi agbègbè rẹ.


Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní Kadeṣi, wọ́n wá sí òkè Hori


Mose bọ́ aṣọ alufaa tí ó wà lọ́rùn Aaroni, ó gbé e wọ Eleasari. Aaroni sì kú sí orí òkè náà, Mose ati Eleasari sì sọ̀kalẹ̀.


Orúkọ aya Amramu ni Jokebedi, ọmọbinrin Lefi tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ijipti. Ó bí Aaroni ati Mose ati Miriamu, arabinrin wọn fún Amramu.


nítorí o ṣàìgbọràn sí àṣẹ mi ninu aṣálẹ̀ Sini. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí mi ní Meriba, ẹ kọ̀ láti fi títóbi agbára mi hàn níwájú àwọn eniyan náà.” (Meriba ni wọ́n ń pe àwọn omi tí ó wà ní Kadeṣi ní aṣálẹ̀ Sini).


Láti Esiongeberi wọ́n lọ sí aṣálẹ̀ Sini, tíí ṣe Kadeṣi.


“Nítorí náà, gbogbo wa wà ní Kadeṣi fún ìgbà pípẹ́.


Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí.


Nítorí pé, ẹ̀yin mejeeji ni ẹ kò hùwà òtítọ́ sí mi láàrin àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí ẹ wà ní odò Meriba Kadeṣi, ní aṣálẹ̀ Sini. Ẹ tàbùkù mi lójú gbogbo àwọn eniyan, ẹ kò bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́ níwájú àwọn eniyan náà.


Ṣugbọn nígbà tí wọn ń bọ̀ láti ilẹ̀ Ijipti, ààrin aṣálẹ̀ ni wọ́n gbà títí wọ́n fi dé Òkun Pupa, tí wọ́n sì fi dé Kadeṣi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan