Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:34 - Yoruba Bible

34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, wọ́n pàgọ́ ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú, olukuluku wà ninu ìdílé tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

34 Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

34 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe gbogbo ohun tí Olúwa pàṣẹ fún Mose, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:34
15 Iomraidhean Croise  

Òun ni ojú kò fi ní tì mí, nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.


Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose, ni àwọn eniyan Israẹli ṣe gbogbo iṣẹ́ náà.


Mose kà wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣálẹ̀ Sinai gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún un.


Kí àwọn ọmọ Israẹli yòókù pa àgọ́ wọn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí, olukuluku ní ibùdó rẹ̀, lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀.


Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose.


Àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn láti aṣálẹ̀ Sinai, wọ́n tò lẹ́sẹẹsẹ. Ìkùukùu náà bá dúró ní aṣálẹ̀ Parani.


Bẹ́ẹ̀ ni ètò ìrìn àjò àwọn ọmọ Israẹli rí nígbà tí wọ́n ṣí kúrò ní ibùdó wọn.


Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.


Ṣugbọn a kò ka àwọn ẹ̀yà Lefi mọ́ àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.


Kò rí ìparun ninu Jakọbu, bẹ́ẹ̀ ni kò rí ìpọ́njú níwájú Israẹli. OLUWA Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, Òun sì ni ọba wọn.


ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,


Àwọn wọnyi ni ìdílé Aaroni ati ti Mose, nígbà tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai.


Àwọn mejeeji ń rìn déédé níwájú Ọlọrun, wọ́n ń pa gbogbo àwọn àṣẹ ati ìlànà Oluwa mọ́ láì kùnà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan