Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:3 - Yoruba Bible

3 Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:3
19 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.


Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni.


Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bi Naṣoni, olórí pataki ninu ẹ̀yà Juda,


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà Juda di ẹ̀yà tí ó lágbára ju gbogbo ẹ̀yà yòókù lọ, tí wọ́n sì ń jọba lórí wọn, sibẹsibẹ ipò àkọ́bí jẹ́ ti àwọn ọmọ Josẹfu).


Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari.


Orúkọ àwọn baálẹ̀-baálẹ̀ náà nìwọ̀nyí: Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Reubẹni.


Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Juda.


Nígbà tí ẹ bá kọ́ fọn fèrè ìdágìrì, àwọn tí wọ́n pa àgọ́ sí ìhà ìlà oòrùn Àgọ́ yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú.


Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọn jẹ́ ẹgbaa mẹtadinlogoji ó lé ẹgbẹta (74,600).


Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.


Ní ọjọ́ kinni, Naṣoni ọmọ Aminadabu, olórí ẹ̀yà Juda mú ẹbọ tirẹ̀ wá.


Ó kó àwọn nǹkan wọnyi kalẹ̀ fún ẹbọ alaafia: akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan. Wọ́n jẹ́ ọrẹ ẹbọ Naṣoni, ọmọ Aminadabu.


Ramu bí Aminadabu, Aminadabu bí Naṣoni, Naṣoni bí Salimoni.


Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan