Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:2 - Yoruba Bible

2 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Kí àwọn ọmọ Israẹli pa àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àsíá ìdílé wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:2
23 Iomraidhean Croise  

Àwọn ọ̀tá rẹ bú ramúramù ninu ilé ìsìn rẹ; wọ́n ta àsíá wọn gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣẹ́gun.


Jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun rẹ, kí o sì mú un ṣẹ, kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó yẹ kí á bẹ̀rù.


Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni, ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni, nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó wà láàrin yín.”


Gbogbo aráyé, ẹ̀yin tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá sókè lórí àwọn òkè, ẹ wò ó, nígbà tí a bá fun fèrè ogun, ẹ gbọ́.


“Ìwọ ọmọ eniyan, ààyè ìtẹ́ mi nìyí, ati ibi ìgbẹ́sẹ̀lé mi. Níbẹ̀ ni n óo máa gbé láàrin àwọn eniyan Israẹli títí lae. Ilé Israẹli tabi àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn wọn, ati òkú àwọn ọba wọn ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mọ́.


Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n, bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀. Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀, bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé.


Ṣugbọn kí ó fi wọ́n ṣe alákòóso Àgọ́ Ẹ̀rí ati àwọn ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀. Àwọn ni yóo máa ru Àgọ́ náà ati gbogbo ohun èlò tí ó wà ninu rẹ̀, wọn yóo sì máa ṣe iṣẹ́ ìsìn níbẹ̀. Wọ́n óo pa ibùdó wọn yí Àgọ́ náà ká.


Àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Juda ni wọ́n kọ́kọ́ ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Naṣoni ọmọ Aminadabu ni olórí wọn.


Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Reubẹni ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni olórí wọn.


Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn.


Ní ìparí, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun Dani ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Ahieseri ọmọ Amiṣadai ni olórí wọn.


OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé:


Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn.


Kí àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ àsíá ẹ̀yà Juda máa pàgọ́ wọn sí ìhà ìlà oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Naṣoni ọmọ Aminadabu ni yóo jẹ́ olórí wọn.


ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,


Nítorí Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun ìdàrúdàpọ̀. Ọlọrun alaafia ni. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ninu gbogbo ìjọ eniyan Ọlọrun,


Ẹ máa ṣe ohun gbogbo létòlétò, ní ọ̀nà tí ó dára.


Nǹkankan tí ó ṣe pataki ni pé kí ẹ jẹ́ kí ìwà yín kí ó jẹ́ irú èyí tí ó bá ìyìn rere Kristi mu, tí ó jẹ́ pé bí mo bá wá tí mo ri yín, tabi bí n kò bá lè wá ṣugbọn tí mò ń gbúròó yín, kí n gbọ́ pé ẹ wà pọ̀ ninu ẹ̀mí kan ati ọkàn kan, ati pé gbogbo yín ń ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹlu igbagbọ ninu iṣẹ́ ìyìn rere.


kò dì mọ́ ẹni tíí ṣe orí, tí ó mú kí gbogbo ara, ati iṣan, ati ẹran-ara wà pọ̀, tí ó ń mú un dàgbà bí Ọlọrun ti fẹ́.


Kí ẹ lè mọ ọ̀nà tí ẹ óo gbà, nítorí pé ẹ kò rin ọ̀nà yìí rí. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ súnmọ́ Àpótí Majẹmu náà jù, ẹ gbọdọ̀ fi àlàfo tí ó tó nǹkan bí ẹgbaa (2,000) igbọnwọ sílẹ̀ láàrin ẹ̀yin ati Àpótí Majẹmu náà.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan