Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:18 - Yoruba Bible

18 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Efuraimu yóo máa wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ní ìsọ̀rí-ìsọrí; Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ní ìhà ìlà-oòrùn: ni ìpín Efraimu yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Efraimu ni Eliṣama ọmọ Ammihudu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:18
13 Iomraidhean Croise  

“Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi.


Tẹkúntẹkún ni wọn yóo wá, tàánútàánú ni n óo sì fi darí wọn pada. N óo mú kí wọn rìn ní etí odò tí ń ṣàn, lójú ọ̀nà tààrà, níbi tí wọn kò ti ní fẹsẹ̀ kọ; nítorí pé baba ni mo jẹ́ fún Israẹli, àkọ́bí mi sì ni Efuraimu.”


Ninu àwọn ọmọ Josẹfu, Eliṣama ọmọ Amihudu ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Efuraimu; Gamalieli ọmọ Pedasuri ni yóo sì jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Manase.


Ninu ẹ̀yà Efuraimu àwọn tí wọ́n tó ẹni ogún ọdún, tí wọ́n tó lọ sójú ogun, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn ní ìdílé-ìdílé


Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Efuraimu ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Eliṣama ọmọ Amihudu ni olórí wọn.


Àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí a kà jẹ́ ọ̀kẹ́ meji ó lé ẹẹdẹgbẹta (40,500).


Ní ọjọ́ keje ni Eliṣama ọmọ Amihudu, olórí àwọn ẹ̀yà Efuraimu mú ọrẹ tirẹ̀ wá.


Eliṣama, ọmọ Amihudu, kó akọ mààlúù meji, ati àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati ọ̀dọ́ àgbò marun-un, ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan sílẹ̀ fún ẹbọ alaafia.


Àkọ́bí rẹ̀ lágbára bí akọ mààlúù, Ìwo rẹ̀ sì dàbí ìwo mààlúù tí ó lágbára, tí yóo fi máa ti àwọn orílẹ̀-èdè títí dé òpin ayé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹgbẹẹgbaarun àwọn ọmọ Efuraimu, ati ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọmọ Manase.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan