Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 2:10 - Yoruba Bible

10 Àsíá ibùdó ẹ̀yà Reubẹni yóo máa wà ní ìhà gúsù ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí; Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ní ìhà gúúsù: ni ìpín ti Reubeni pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Reubeni ni Elisuri ọmọ Ṣedeuri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 2:10
8 Iomraidhean Croise  

Reubẹni ni àkọ́bí Jakọbu, (Ṣugbọn nítorí pé Reubẹni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn obinrin baba rẹ̀, baba rẹ̀ gba ipò àgbà lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Josẹfu. Ninu àkọsílẹ̀ ìdílé, a kò kọ orúkọ rẹ̀ sí ipò àkọ́bí.


Orúkọ àwọn baálẹ̀-baálẹ̀ náà nìwọ̀nyí: Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni yóo jẹ́ olórí láti inú ẹ̀yà Reubẹni.


Lẹ́yìn náà ni àwọn tí wọ́n wà lábẹ́ ọ̀págun ẹ̀yà Reubẹni ṣí, wọ́n tò ní ìsọ̀rí-ìsọ̀rí. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni olórí wọn.


Bí ẹ bá fọn fèrè ìdágìrì lẹẹkeji, àwọn tí wọ́n pàgọ́ sí ìhà gúsù yóo ṣí, wọn yóo sì tẹ̀síwájú. Ìgbàkúùgbà tí ẹ bá fẹ́ tẹ̀síwájú ni kí ẹ máa fọn fèrè ìdágìrì.


Àwọn ọmọ ogun tí a kà ninu wọ́n jẹ́ ẹgbaa mẹtalelogun ó lé ẹẹdẹgbẹta (46,500).


Ní ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olórí ẹ̀yà Reubẹni mú ọrẹ tirẹ̀ wá.


Ó sì mú akọ mààlúù meji, àgbò marun-un, òbúkọ marun-un ati akọ ọ̀dọ́ aguntan marun-un ọlọ́dún kan wá fún ẹbọ alaafia. Ọrẹ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri nìyí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan