Lẹ́yìn náà, Àgọ́ Ẹ̀rí yóo ṣí, pẹlu àgọ́ àwọn ọmọ Lefi. Bí wọ́n ti pàgọ́ yí Àgọ́ náà ká, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóo ṣe máa ṣí, olukuluku ní ipò rẹ̀, pẹlu àsíá ẹ̀yà rẹ̀.
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli yóo bá pàgọ́ wọn, kí olukuluku máa pàgọ́ rẹ̀ lábẹ́ àsíá ẹ̀yà rẹ̀, ati lábẹ́ ọ̀págun ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n máa pàgọ́ wọn yí Àgọ́ náà ká.