Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:7 - Yoruba Bible

7 Lẹ́yìn náà kí ó wẹ̀, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì pada sí ibùdó. Ṣugbọn yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nigbana ni ki alufa na ki o fọ̀ ãṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, lẹhin na ki o si wá si ibudó, ki alufa na ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Lẹ́yìn náà, àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ́yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:7
19 Iomraidhean Croise  

“Àwọn ni wọ́n lè sọ yín di aláìmọ́; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ẹni náà fọ aṣọ rẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ninu àwọn ẹranko tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ mẹrin rìn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti ń fi ẹsẹ̀ mẹrẹẹrin rìn tí wọ́n sì ní èékánná jẹ́ aláìmọ́ fun yín; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Bí ẹnikẹ́ni bá gbé òkú wọn, kí ó fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; ohun àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fun yín.


Wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín ninu gbogbo ohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkú wọn di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ohunkohun tí òkú wọn bá jábọ́ lé lórí di aláìmọ́, ìbáà jẹ́ ohun èlò igi, tabi aṣọ tabi awọ, tabi àpò, irú ohun èlò yòówù tí ó lè jẹ́, ó níláti di fífọ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́, lẹ́yìn náà, yóo di mímọ́.


“Bí ọ̀kankan ninu àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ bá kú, ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan òkú rẹ̀ di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ òkú ẹran náà níláti fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹni tí ó bá ru òkú ẹran náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá wọ ilé náà lẹ́yìn tí alufaa ti tì í pa, yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan ibùsùn rẹ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara kan irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tabi irú ẹni bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́; kò sì ní jẹ ninu àwọn ohun mímọ́ náà títí tí yóo fi wẹ̀.


Ẹni tí ó bá kó eérú náà jọ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Èyí yóo jẹ́ ìlànà fún àwọn ọmọ Israẹli ati fún àwọn àlejò tí ó wà láàrin wọn títí lae.


Yóo sì bu omi náà wọ́n aláìmọ́ náà ní ọjọ́ kẹta ati ikeje. Ní ọjọ́ keje, yóo wẹ̀, yóo sì di mímọ́. Aláìmọ́ náà yóo fọ aṣọ rẹ̀, yóo sì wẹ̀ ninu omi, yóo sì di mímọ́ ní ìrọ̀lẹ́.


Ẹ gbọdọ̀ pa ìlànà yìí mọ́ láti ìrandíran. Ẹni tí ó bá wọ́n omi ìwẹ̀nùmọ́ náà sí aláìmọ́ lára gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan omi náà yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.


Ohunkohun tí aláìmọ́ bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fọwọ́ kan ohun tí aláìmọ́ náà bá fọwọ́ kàn yóo di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.”


Ẹni tí ó sun mààlúù náà gbọdọ̀ wẹ̀ kí ó sì fọ aṣọ rẹ̀, òun náà yóo jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà.


Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan