Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:6 - Yoruba Bible

6 Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ki alufa na ki o mú igi opepe, ati hissopu, ati ododó, ki o si jù u sãrin ẹgbọrọ abomalu ti a nsun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Àlùfáà yóò mú igi kedari, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárín ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:6
6 Iomraidhean Croise  

Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.


OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná, yóo di funfun bí ẹfun. Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì, yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.


Alufaa yóo pàṣẹ pé kí wọ́n bá ẹni tí wọ́n fẹ́ ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún mú ẹyẹ mímọ́ meji wá ati igi kedari, pẹlu aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu.


Nígbà tí alufaa bá fẹ́ sọ ilé náà di mímọ́, yóo mú ẹyẹ kéékèèké meji ati igi kedari ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́ kan, ati ewé hisopu,


Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan