Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:2 - Yoruba Bible

2 “Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Eyi ni ìlana ofin, ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú ẹgbọrọ abomalu pupa kan tọ̀ ọ wá, alailabawọ́n, ati alailabùku, ati lara eyiti a kò ti dì àjaga mọ́:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Èyí ni ohun tí òfin Olúwa pàṣẹ béèrè lọ́wọ́ yín: Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, kí wọn mú ẹgbọrọ ọ̀dọ́ màlúù pupa tí kò lábùkù tàbí àbàwọ́n, lára èyí tí a kò tí ì di àjàgà mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:2
21 Iomraidhean Croise  

Ọ̀dọ́ aguntan tabi àwọ́nsìn ewúrẹ́ náà kò gbọdọ̀ lábàwọ́n, ó lè jẹ́ àgbò tabi òbúkọ ọlọ́dún kan.


OLUWA ní, “Ẹ wá ná, ẹ jẹ́ kí á jọ sọ àsọyé pọ̀. Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ pọ́n bí iná, yóo di funfun bí ẹfun. Bí ó tilẹ̀ pupa bí aṣọ àlàárì, yóo di funfun bí irun ọmọ aguntan funfun.


“Ó di ẹ̀ṣẹ̀ mi bí àjàgà, ó gbé e kọ́ mi lọ́rùn, ó sì sọ mí di aláìlágbára. OLUWA ti fi mí lé àwọn tí n kò lè dojú kọ lọ́wọ́.


“Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo aguntan tabi agbo ewúrẹ́ ni ó ti mú ẹran fún ẹbọ sísun rẹ̀, akọ tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú.


“Bí ó bá jẹ́ pé láti inú agbo mààlúù ni ó ti mú un láti fi rú ẹbọ sísun, akọ mààlúù tí kò ní àbààwọ́n ni kí ó mú wá, kí ó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ láti fi rúbọ, kí ó lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú OLUWA.


Yóo mú ẹyẹ tí ó wà láàyè ati igi kedari, ati aṣọ pupa tẹ́ẹ́rẹ́, ati ewé hisopu, yóo pa wọ́n pọ̀, yóo sì tì wọ́n bọ inú ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ tí wọ́n pa lórí odò tí ń ṣàn.


OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé,


Kí alufaa ju igi kedari ati hisopu ati aṣọ pupa sinu iná náà.


Eleasari bá sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ ìlànà tí OLUWA ti fi lélẹ̀ láti ẹnu Mose.


Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí.


Kí àwọn àgbààgbà ìlú tí ó bá súnmọ́ ibẹ̀ jùlọ wá ọ̀dọ́ akọ mààlúù kan tí ẹnikẹ́ni kò tíì so àjàgà mọ́ lọ́rùn láti fi ṣiṣẹ́ rí,


Irú olórí alufaa bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ wá. Ẹni mímọ́; tí kò ní ẹ̀tàn, tí kò ní àbùkù, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kẹ́gbẹ́, tí a gbé ga kọjá àwọn ọ̀run.


Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.


Ohun tí a fi rà yín ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, ẹ̀jẹ̀ iyebíye bíi ti ọ̀dọ́-aguntan tí kò ní àléébù, tí kò sì ní àbààwọ́n.


Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí.


ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan