Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 19:16 - Yoruba Bible

16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ẹni tí wọ́n fi idà pa, tabi òkú, tabi egungun òkú tabi ibojì òkú ninu pápá yóo di aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ẹnikẹni ti o ba si fọwọkàn ẹnikan ti a fi idà pa ni gbangba igbẹ́, tabi okú kan, tabi egungun ẹnikan, tabi isà-okú, yio jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà ní ìta tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹni tí a fi idà pa tàbí ẹni tí ó kú ikú àtọ̀runwá, tàbí bí ẹnìkan bá fi ọwọ́ kan egungun òkú ènìyàn tàbí isà òkú, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 19:16
12 Iomraidhean Croise  

Ẹ jáde, ẹ jáde ẹ kúrò níbẹ̀, ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan, ẹ jáde kúrò láàrin rẹ̀, kí ẹ sì wẹ ara yín mọ́, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò OLUWA.


Lẹ́yìn tí alufaa bá di aláìmọ́, yóo dúró fún ọjọ́ meje, lẹ́yìn náà yóo di mímọ́.


OLUWA sọ fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn alufaa, àwọn ọmọ Aaroni pé, “Ẹnikẹ́ni ninu wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí ikú àwọn eniyan rẹ̀.


“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú yóo jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ meje.


Gbogbo ohun èlò tí ó bá wà ninu àgọ́ náà tí wọn kò fi ọmọrí dé di aláìmọ́.


Ǹjẹ́ nisinsinyii gbogbo àwọn tí ó bá ti paniyan tabi tí ó ti fọwọ́ kan òkú láàrin yín yóo dúró lẹ́yìn ibùdó fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ kẹta ati ọjọ́ keje, àwọn ati obinrin tí wọ́n mú lójú ogun yóo ṣe ìwẹ̀nùmọ́.


“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n lé gbogbo àwọn adẹ́tẹ̀ kúrò ní ibùdó wọn, gbogbo àwọn tí ó ni ọyún lára ati ẹnikẹ́ni tí ó di aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú.


Ní gbogbo ọjọ́ tí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ fún OLUWA, kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú:


Ṣugbọn àwọn kan wà tí wọn kò lè bá wọn ṣe ọdún náà nítorí pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ọwọ́ kan òkú. Wọ́n wá sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni, wọ́n sì sọ fún wọn pé,


“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn wọnyi. Ẹ dàbí àwọn ibojì tí a kùn ní funfun, tí ó dùn-ún wò lóde, ṣugbọn inú wọn kún fún egungun òkú ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin.


Ẹ gbé! Nítorí ẹ dàbí ibojì tí kò ní àmì, tí àwọn eniyan ń rìn lórí wọn, tí wọn kò mọ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan