Ẹ kò ní jẹ̀bi nígbà tí ẹ bá jẹ ẹ́, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti san ìdámẹ́wàá ninu èyí tí ó dára jù. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà sọ ọrẹ mímọ́ àwọn ọmọ Israẹli di àìmọ́ nípa jíjẹ wọ́n láìsan ìdámẹ́wàá wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ óo kú.”
“Ìlànà tí èmi OLUWA fi lélẹ̀ nìyí: Ẹ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n mú ẹgbọ̀rọ̀ abo mààlúù pupa kan wá. Kò gbọdọ̀ ní àbààwọ́n kankan, wọn kò sì gbọdọ̀ tíì fi ṣiṣẹ́ rí.