Numeri 18:9 - Yoruba Bible9 Ninu gbogbo ẹbọ mímọ́ tí a kò sun lórí pẹpẹ, ẹbọ ọrẹ, ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, tí wọn ń rú sí mi yóo jẹ́ mímọ́ jùlọ fún ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ. Faic an caibideilBibeli Mimọ9 Eyi ni yio ṣe tirẹ ninu ohun mimọ́ julọ, ti a mú kuro ninu iná; gbogbo ọrẹ-ẹbọ wọn, gbogbo ẹbọ ohunjijẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn, ati gbogbo ẹbọ ẹbi wọn, ti nwọn o mú fun mi wá, mimọ́ julọ ni yio jasi fun iwọ ati fun awọn ọmọ rẹ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 Ìwọ ni kí o ni ìpín ọrẹ mímọ́ jùlọ tí a mú kúrò ní ibi iná, nínú gbogbo ọrẹ tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ mímọ́ jùlọ, yálà ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹbọ ẹ̀bi, ìpín wọ̀nyí jẹ́ ti ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.