Numeri 18:8 - Yoruba Bible8 OLUWA sọ fún Aaroni pé, “Mo ti fún ọ ní gbogbo ohun tí ó kù ninu àwọn ohun tí wọ́n bá fi rúbọ sí mi, ati gbogbo ohun tí àwọn ọmọ Israẹli bá yà sọ́tọ̀. Ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni mo fún gẹ́gẹ́ bi ìpín yín títí lae. Faic an caibideilBibeli Mimọ8 OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Kiyesi i, emi si ti fi itọju ẹbọ igbesọsoke mi fun ọ pẹlu, ani gbogbo ohun mimọ́ awọn ọmọ Israeli, iwọ li emi fi wọn fun ni ipín, ati fun awọn ọmọ rẹ, bi ipín lailai. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní8 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Aaroni pé, “Èmi fúnra mi ti fi ọ́ ṣọ́ ìdí gbogbo ẹbọ tí a bá mú wá fún gbogbo ọrẹ mímọ́ tí àwọn ọmọ Israẹli bá fún mi, mo fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ tí yóò máa ṣe. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, kí o wí níwájú OLUWA Ọlọrun rẹ pé, ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá tíí ṣe ohun ìyàsímímọ́ ni mo ti mú kúrò ninu ilé mi, mo sì ti fi fún àwọn ọmọ Lefi ati àwọn àlejò, ati àwọn aláìní baba, ati àwọn opó, gẹ́gẹ́ bíi gbogbo àṣẹ tí o pa fún mi. N kò rú èyíkéyìí ninu àwọn òfin rẹ, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì gbàgbé wọn.