Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:7 - Yoruba Bible

7 Ṣugbọn ìwọ pẹlu àwọn ọmọ rẹ nìkan ni alufaa ti yóo máa ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ ìrúbọ ati níbi aṣọ ìbòjú. Èyí ni yóo jẹ́ iṣẹ́ yín nítorí ẹ̀bùn ni mo fi iṣẹ́ alufaa ṣe fun yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ àwọn ohun mímọ́ yóo kú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ni yóò mójútó iṣẹ́ àlùfáà yín fún gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ibi pẹpẹ àti ti ẹ̀yin aṣọ títa, ẹ ó sì máa ṣiṣẹ́ ibi pẹpẹ àti nínú aṣọ tí a ta. Mo fún ọ ní iṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn. Ṣùgbọ́n àlejò tí ó bá súnmọ́ tòsí ibi ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ni a ó pa.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:7
28 Iomraidhean Croise  

Ẹ̀yin ìdílé Aaroni, ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, òun ni olùrànlọ́wọ́ ati aláàbò yín.


“Lẹ́yìn náà, pe Aaroni arakunrin rẹ sọ́dọ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ wọnyi: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọmọ Israẹli, kí wọ́n sì jẹ́ alufaa mi.


dì wọ́n lámùrè, kí o sì dé wọn ní fìlà. Bẹ́ẹ̀ ni kí o ṣe ya Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, atọmọdọmọ wọn yóo sì máa ṣe alufaa mi.


“Ṣugbọn àwọn alufaa ọmọ Lefi láti ìran Sadoku, tí wọn ń tọ́jú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ṣáko lọ kúrò lọ́dọ̀ mi, àwọn ni yóo máa lọ sí ibi pẹpẹ mi láti rúbọ sí mi. Àwọn ni wọn óo máa fi ọ̀rá ati ẹ̀jẹ̀ rú ẹbọ sí mi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


Àwọn ni wọn óo máa wọ ibi mímọ́ mi, wọn óo máa lọ sí ibi tabili mi, tí wọn óo máa ṣiṣẹ́ iranṣẹ, wọn óo sì máa pa àṣẹ mi mọ́.


Ẹ kò tọ́jú àwọn ohun mímọ́ mi, àwọn àlejò ni ẹ ti fi ṣe alákòóso níbẹ̀.


“Sọ fún Aaroni arakunrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wọ ibi mímọ́ jùlọ, tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa, níwájú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí àpótí ẹ̀rí nígbà gbogbo, kí ó má baà kú; nítorí pé n óo fi ara hàn ninu ìkùukùu, lórí ìtẹ́ àánú.


Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa.


OLUWA ní, “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ ṣí lọ siwaju, kí àwọn ọmọ Lefi tú Àgọ́ Ẹ̀rí palẹ̀ kí wọ́n rù ú. Nígbà tí ẹ bá sì dúró, àwọn ọmọ Lefi ni kí wọn pa Àgọ́ náà. Bí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe ọmọ Lefi bá súnmọ́ tòsí wọn, pípa ni kí wọ́n pa á.


Èyí sì jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣe ọmọ Aaroni kò gbọdọ̀ wá siwaju pẹpẹ OLUWA láti sun turari, kí ẹni náà má baà dàbí Kora ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti rán Mose pé kí ó sọ fún Eleasari.


OLUWA sọ fún Aaroni pé, “O kò gbọdọ̀ gba ohun ìní kan tí eniyan lè jogún tabi ilẹ̀ ní Israẹli. Èmi OLUWA ni yóo jẹ́ ìpín ati ìní rẹ láàrin àwọn ọmọ Israẹli.”


Wọn óo máa jíṣẹ́ fún ọ, wọn óo sì máa ṣe iṣẹ́ wọn ninu Àgọ́ Ẹ̀rí, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ọ̀kan ninu àwọn ohun mímọ́ tí ó wà ninu ibi mímọ́ tabi pẹpẹ ìrúbọ, kí gbogbo wọn má baà kú.


Yan Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí ẹ pa á.”


Mose pẹlu Aaroni ati àwọn ọmọ wọn yóo pa àgọ́ tiwọn sí ìhà ìlà oòrùn, níwájú Àgọ́ Àjọ. Àwọn ni yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli ní ibi mímọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ibi mímọ́, pípa ni kí wọ́n pa á.


Ẹ máa wo aláìsàn sàn; ẹ máa jí àwọn òkú dìde; ẹ máa sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́; ẹ máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ rí agbára wọnyi gbà. Ọ̀fẹ́ ni kí ẹ máa lò wọ́n.


Johanu fèsì pé, “Kò sí ẹni tí ó lè rí ohunkohun gbà àfi ohun tí Ọlọrun bá fún un.


Nítorí èmi tí mo kéré jùlọ ninu gbogbo àwọn onigbagbọ ni Ọlọrun fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, pé kí n máa waasu fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa àwámárìídìí ọrọ̀ Kristi.


Wọn kò ní ní ìpín láàrin àwọn arakunrin wọn. OLUWA ni ìpín tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.


Kò sí ẹni tíí yan ara rẹ̀ sí ipò yìí. Ṣugbọn àwọn tí Ọlọrun bá pè ni à ń yàn, bíi Aaroni.


Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”


Mo bẹ̀ yín pé kí ẹ ṣe ìtọ́jú ìjọ Ọlọrun tí ẹ wà ninu rẹ̀. Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín bí alabojuto. Kì í ṣe àfipáṣe ṣugbọn tinútinú bí Ọlọrun ti fẹ́. Ẹ má ṣe é nítorí ohun tí ẹ óo rí gbà níbẹ̀, ṣugbọn kí ẹ ṣe é pẹlu ìtara àtọkànwá.


Ẹ má ṣe é bí ẹni tí ó fẹ́ jẹ́ aláṣẹ lórí àwọn tí ó wà lábẹ́ yín ṣugbọn ẹ ṣe é bí àpẹẹrẹ fún ìjọ.


Ninu gbogbo ẹ̀yà tí ó wà ní Israẹli, ìdílé baba rẹ nìkan ni mo yàn láti jẹ́ alufaa mi, pé kí ẹ máa ṣe iṣẹ́ alufaa níbi pẹpẹ, kí ẹ máa sun turari kí ẹ máa wọ ẹ̀wù efodu, kí ẹ sì máa wádìí nǹkan lọ́wọ́ mi. Mo fún wọn ní gbogbo ẹbọ sísun tí àwọn ọmọ Israẹli bá rú sí mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan