Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:16 - Yoruba Bible

16 Àwọn òbí yóo ra àwọn ọmọ wọn pada nígbà tí wọ́n bá pé ọmọ oṣù kan. Owó ìràpadà wọn jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli marun-un. Ìwọ̀n tí wọn ń lò ní ibi mímọ́, èyí tíí ṣe ogún ìwọ̀n gera ni kí wọ́n fi wọ̀n ọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Gbogbo awọn ti a o ràsilẹ, lati ẹni oṣù kan ni ki iwọ ki o ràsilẹ, gẹgẹ bi idiyelé rẹ, li owo ṣekeli marun, nipa ṣekeli ibi-mimọ́ (ti o jẹ́ ogun gera).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nígbà tí wọ́n bá pé oṣù kan, o gbọdọ̀ rà wọ́n padà ní iye owó ìràpadà tí í ṣe ṣékélì márùn-ún fàdákà, gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ tí ó wọn ìwọ̀n ogún (20) gera.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:16
9 Iomraidhean Croise  

Ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí o bá kà yóo san ni: ìdajì ṣekeli, tí a fi ìwọ̀n ilé OLUWA wọ̀n, (tí ó jẹ́ ogún ìwọ̀n gera fún ìwọ̀n ṣekeli kan), ìdajì ṣekeli náà yóo sì jẹ́ ti OLUWA.


Gbogbo wúrà tí wọ́n lò fún kíkọ́ àgọ́ náà jẹ́ ìwọ̀n talẹnti mọkandinlọgbọn ati ẹẹdẹgbẹrin ìwọ̀n ṣekeli ó lé ọgbọ̀n (730), ìwọ̀n tí wọn ń lò ninu àgọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n.


“Ogún òṣùnwọ̀n gera ni yóo wà ninu òṣùnwọ̀n ṣekeli kan. Ṣekeli marun-un gbọdọ̀ pé ṣekeli marun-un. Ṣekeli mẹ́wàá sì gbọdọ̀ pé ṣekeli mẹ́wàá; òṣùnwọ̀n mina sì gbọdọ̀ pé aadọta ṣekeli.


“Ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ninu ibi mímọ́ ni kí ẹ máa lò láti wọn ohun gbogbo: Ogún ìwọ̀n gera ni yóo jẹ́ ìwọ̀n ṣekeli kan.


“Gbogbo àwọn àkọ́bí eniyan tabi ti ẹranko tí àwọn ọmọ Israẹli bá mú wá fún mi, tìrẹ ni. Ṣugbọn o óo gba owó ìràpadà dípò àkọ́bí eniyan ati ti ẹranko tí ó bá jẹ́ aláìmọ́.


Ṣugbọn wọn kò ní ra àwọn àkọ́bí mààlúù, ati ti aguntan ati ti ewúrẹ́ pada, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Da ẹ̀jẹ̀ wọn sí ara pẹpẹ kí o sì fi ọ̀rá wọn rú ẹbọ sísun olóòórùn dídùn sí mi.


Níwọ̀n ìgbà tí àwọn àkọ́bí Israẹli fi igba ó lé mẹtalelaadọrin (273) pọ̀ ju àwọn ọmọ Lefi lọ, wọ́n níláti rà wọ́n pada.


Kí o gba ṣekeli marun-un-marun-un lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ṣekeli tí wọn ń lò ní ibi mímọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan