Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Numeri 18:12 - Yoruba Bible

12 “Mo fún ọ ní gbogbo èso àkọ́so tí àwọn ọmọ Israẹli ń mú wá fún mi lọdọọdun, ati òróró tí ó dára jùlọ, ọtí waini tí ó dára jùlọ, ati ọkà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Gbogbo oróro daradara, ati gbogbo ọti-waini daradara, ati alikama, akọ́so ninu wọn ti nwọn o mú fun OLUWA wá, iwọ ni mo fi wọn fun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 “Mo fún ọ ní gbogbo òróró tí ó dára jùlọ àti gbogbo ọtí tuntun dáradára jùlọ àti ọkà tí wọ́n mú wá fún Olúwa ní àkọ́so ohun ọ̀gbìn wọn tí wọ́n kórè.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Numeri 18:12
19 Iomraidhean Croise  

Kí Ọlọrun fún ọ ninu ìrì ọ̀run ati ilẹ̀ tí ó dára ati ọpọlọpọ ọkà ati ọtí waini.


Ọkunrin kan wá láti Baaliṣaliṣa, ó mú burẹdi àkọ́so èso wá fún eniyan Ọlọrun, ati ogún burẹdi tí a fi ọkà-baali ṣe ati ṣiiri ọkà tuntun ninu àpò rẹ̀. Eliṣa bá wí pé, “Ẹ kó wọn fún àwọn ọmọkunrin, kí wọ́n jẹ ẹ́.”


Ní kété tí àṣẹ yìí tàn káàkiri, wọ́n mú ọpọlọpọ àkọ́so ọkà, ati ọtí ati òróró ati oyin, ati àwọn nǹkan irè oko mìíràn wá. Wọ́n tún san ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan tí wọ́n ní.


Ó jẹ́ kí alaafia wà ní ààlà ilẹ̀ rẹ, ó sì fi oúnjẹ tí ó dára bọ́ ọ lábọ̀ọ́yó.


Ṣugbọn èmi ó máa fi ọkà tí ó dára jùlọ bọ yín, n óo sì fi oyin inú àpáta tẹ yín lọ́rùn.”


“O kò gbọdọ̀ jáfara láti mú ninu ọpọlọpọ ọkà rẹ ati ọpọlọpọ ọtí waini rẹ láti fi rúbọ sí mi. “O níláti fún mi ní àkọ́bí rẹ ọkunrin pẹlu.


“Ohunkohun tí o bá kọ́ kórè ninu oko rẹ, ilé OLUWA Ọlọrun rẹ ni o gbọdọ̀ mú un wá. “O kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi wàrà ìyá rẹ̀.


“Ẹ gbọdọ̀ mú àkọ́so oko yín wá sí ilé OLUWA Ọlọrun yín. “Ẹ kò gbọdọ̀ bọ ọmọ ẹran ninu omi ọmú ìyá rẹ̀.”


Gbogbo àkọ́so oniruuru èso ati oniruuru ọrẹ gbọdọ̀ jẹ́ ti àwọn alufaa. Ẹ sì gbọdọ̀ fún àwọn alufaa mi ní àkọ́pò ìyẹ̀fun yín kí ibukun lè wà ninu ilé yín.


O lè mú wọn wá fún OLUWA gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so oko, ṣugbọn wọn kò gbọdọ̀ fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ bí ẹbọ olóòórùn dídùn.


Bí o bá fẹ́ fi àkọ́so oko rẹ rú ẹbọ ohun jíjẹ sí OLUWA, ninu ṣiiri ọkà àkọ́so oko rẹ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa ni kí o ti mú, kí o yan án lórí iná.


Ẹ óo mú burẹdi meji tí wọ́n fi ìdámárùn-ún ìwọ̀n efa ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára ṣe wá fún ẹbọ fífì; àwọn àkàrà náà yóo ní ìwúkàrà ninu, ẹ óo mú wọn tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí àkọ́so oko yín.


Alufaa yóo fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA, pẹlu burẹdi tí ẹ fi àkọ́so ọkà ṣe, ati àgbò meji náà, wọn yóo jẹ́ ọrẹ mímọ́ fún OLUWA, tí a óo yà sọ́tọ̀ fún àwọn alufaa.


“Ohun tí yóo jẹ́ ti àwọn alufaa lára ẹran tí àwọn eniyan bá fi rúbọ nìyí, kì báà jẹ́ akọ mààlúù tabi aguntan ni wọ́n wá fi rúbọ, wọn yóo fún alufaa ní apá ati ẹ̀rẹ̀kẹ́ mejeeji, ati àpòlùkú rẹ̀.


Kí ẹ fún àwọn alufaa ní àkọ́so oko yín, ati àkọ́pọn ọtí waini yín, ati àkọ́ṣe òróró yín, ati irun aguntan tí ẹ bá kọ́kọ́ rẹ́.


mú ninu àkọ́so èso ilẹ̀ náà sinu agbọ̀n kan, kí o sì gbé e lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun rẹ yóo yàn pé kí ẹ ti máa sin òun.


Wọn rí ọpọlọpọ wàrà lára mààlúù wọn, ati ọ̀pọ̀ omi wàrà lára ewúrẹ́ wọn, ó fún wọn ní ọ̀rá ọ̀dọ́ aguntan ati ti àgbò, ó fún wọn ní mààlúù Baṣani, ati ewúrẹ́, ati ọkà tí ó dára jùlọ, ati ọpọlọpọ ọtí waini.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan